US Equality Day: Obìnrin 140,000 kọ̀wé bèèrè àtìlẹyìn àwọn olórí orílẹ̀èdè àgbáyé

Ti a ba n sọrọ bi awọn obinrin lorilẹede Naijiria se n kopa si ninu eto oselu, a lee ni wọn n ja fitafita, ti wọn si n kuro ni ipo oludibo lasan bọ si ipo oloselu, ẹni to n gbegba ibo ati ẹni to n se akoso ilu.
Ta ba ni ka mọọ ka ni eni, eji, ẹta, o ni iye awọn obinrin to ti gbegba apoti ibo, ninu wọn si la ti ri Sarah Jubril, Olurẹmi Sonaiya, Oby Ezekwesili, Olurẹmi Tinubu, Olurẹmi Olujinmi, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹjọ ọdọọdun, eyiun ayajọ oni, si ni orilẹede Amẹrika ya sọtọ fun ayajọ ọjọ ibaradọgba awọn obinrin pẹlu ọkunrin ninu eto oselu.

Amọ ibeere to wa n gba ẹnu ọpọ eeyan ni pe, se awọn obinrin ti saayan to lorilẹede Naijiria, lati kopa ninu oselu?
Iwadi fihan pe awọn obinrin ti n se gudugudu meje ati ya ya ya mẹfa lagbo oselu lati ba awọn ọkunrin fi ẹgbẹkẹgbẹ ninu eto oselu ati idibo, ti wọn si ti n ri ọwọ yọ, paapa lati igba ti orilẹede wa ti gba ominira.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọsilẹ fihan pe lasiko eto idibo gbogbogboo to waye ni ọdun 2019, awọn obinrin to kopa ninu ibo sile asofin agba jẹ ojilerugba o din mẹjọ (232), tile asoju-sofin jẹ ojilelẹẹdẹgbẹrun o din mẹjọ ( 532), nigba ti mejilelọgbọn (32) tiraka lati di gomina ipinlẹ.
Ni ọpọ orilẹede agbaye, ofin ibaradọgba fun awọn obinrin ati ọmọdebinrin pẹlu awọn ọkunrin ni ko si rara, eyi to lee fidi ẹtọ ati anfaani ọgbọọgba ti wọn ni pẹlu awọn ọkunrin mulẹ, nibi to ba si wa, amusẹ ofin naa yoo mu wahala lọwọ.

Fun apẹẹrẹ, ni orilẹede wa Naijiria, bi o tilẹ jẹ pe awọn obinrin n gberi diẹ diẹ nilẹ Naijiria nidi oselu yii, sibẹ aba ofin to wa fun ipese anfaani ibaradọgba laarin akọ ati abo lo ti fori sanpọn lọpọ igba nile asofin apapọ.
Idi ni pe se ni awọn asofin naa n kọ ofin yii silẹ, ti ọpọ awọn ọmọ ile asofin ti wọn jẹ ọkunrin si n fi ẹnu abuku kun aba naa nigbakuugba ti wọn ba tun gbe wa siwaju ile.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ yii, Abiọla Akiọde tii se agbẹjọro ati ajafẹtọ obinrin woye pe, ni orilẹede Afirika, awọn obinrin gbọdọ kọkọ fi imọ sọkan lati ri pe ofin ti yoo fun wọn ni anfaani ọgbọọgba pẹlu awọn ọkunrin di mimusẹ ninu ijọba ta wa yii.
Wayi o, ninu ilakaka wọn lati ri pe ofin naa dohun ni ọpọ orilẹede to wa nilẹ Afirika, awọn obinrin ajafẹtọ ẹni to to marundinlaadọta lati orilẹede mẹẹdogun, gbimọ pọ kọ iwe kan sawọn asaaju orilẹede lagbaye, losu Kẹta ọdun 2019.

Iwe naa lo wa lati ran wọn leti ileri wọn pe, awọn yoo ja fun aise idajọ ododo lori ọrọ to kan obinrin, ti wọn yoo si ri daju pe ibaradọgba ati ironilagbara wa fawọn obinrin ati ọdọbinrin ko to di ọdun 2030.
Wọn ni tẹni ba dakẹ, ti ara rẹ yoo ba dakẹ, eyi lo tun mu ki awọn obinrin yii kesi akẹẹgbẹ wọn bii ẹgbẹrun lọna ogoje ninu ẹgbẹrun lọna aadọjọ ti wọn fi oju sun lori itakun agbaye, lati buwọlu ibeere wọn ọhun eyi ti wọn gbe siwaju awọn olori orilẹede lagbaye.
- Owó dé! ₦30,000 owó oṣù yòó bẹ̀rẹ̀ ní September - Alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ l‘Ekiti
- Láti January lọ, gbogbo ẹni tó bá ra ọjà lórí ayélujára yóò máa sanwó orí - FIRS
- Aṣojú Seyí Makinde lásan ní mo jẹ, òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún mi - Ọ̀dọ́mọdé Kọmísánà
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
Ti ọpọ orilẹede lagbaye ba sọ aba ibaradọgba awọn obinrin yii di ofin, o daju pe ọpọ anfaani ni gbogbo agbaye yoo ri ninu rẹ.
Iwadi kan tiẹ ti safihan rẹ pe, ofin ibaradọgba yoo mu ki igbe aye idẹrun wa fun ti ọkunrin ati obinrin, ti wọn yoo si ni itẹlọrun pẹlu ipokipo ti wọn ba wa.












