Jollof rice: Ṣé lóòtọ́ ni ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù Ghana dùn ju ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù Nàìjíríà lọ?

Irẹsi Jollof

Oríṣun àwòrán, @EarlJoey_.

Kii ṣe ana ni ariyanjiyan laarin awọn eeyan, paapaa julọ, awọn ọmọ orilẹede Naijiria ati Ghana ti n waye lori irẹsi jọlọọfu ẹni to dun julọ ninu ti orilẹede mejeeji.

Amọṣa, ariyanjiyan naa n dabi eyi ti wọn ti wa ojutu si bayii lẹyin ti alase ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan lati orilẹede Ghana, Sika Mortoo, fi ajulọ han akẹgbẹ rẹ lati orilẹede Naijiria, nibi idije ase kan to waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idije Onga Jollof Battle to waye lopin ọsẹ to kọja nilu Accra laarin awọn alase meji naa lati mọ orilẹ€de ti irẹsi jọlọọfu rẹ dun julọ.

Gbajugbaja ounjẹ, ari ma lee lọ ni irẹsi jọlọọfu ni ẹkun iwọ oorun Afirika eyi ti wọn maa n fi irẹsi, tomato atawọn eroja miran ṣe.

idije irẹsi jọlọọfu laarin Naijiria ati Ghana

Oríṣun àwòrán, PrOMAISODOR GHANA

Ilumọọka ni irẹsi jọlọọfu laarin awọn ọmọ orilẹede bii Senegal, Ghana, Naijiria, Gambia, Sierra Leone, Liberia ati cameroon.

Fun ọdun diẹ sẹyin bayii ni ariyanjiyan ti n waye laarin awọn ọmọ Naijiria ati Ghana lori ikoko irẹsi jọlọọfu to ṣee jẹ ni ajẹpọnula julọ laarin orilẹede mejeeji.

idije irẹsi jọlọọfu laarin Naijiria ati Ghana

Oríṣun àwòrán, PrOMAISODOR GHANA

Lẹyin ti awọn adajọ ṣe itọwo abọ irẹsi jọlọọfu ti wọn gbe wa, awọn mẹtẹẹta lo panupọ ṣalaye pe irẹsi jọlọọfu ti ghana lọba.

Orilẹede Ghana, Naijiria ati South Africa ni awọn adajs nibi idije naa ti wa.

Sika Mortoo to gbe igba oroke nibi idije ase naa gba ẹbun owo ẹgbẹrun meji dọla ($2000), ọmọ Naijiria to baa dije, Chef Turay, naa si gba Ẹgbẹrun kan dọla ($1000).