COZA RAPE: Ilé ọlọpàá ìlú Abuja pé Fatoyinbo fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Olùṣọ́-àgùntàn Biodun Fatoyinbo ti ìjọ Commonwealth of Zion Church tí fára rẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ ọlọpàá fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lóri èsùn ìfipábánilòpọ̀ Busola Dakolo fí kàn -àn.
Sááju ni Fatoyinbo ti ran àwọn asojú rẹ̀ lọ sí olú ilé iṣẹ́ ọlọpàá ẹka CID tí ìlú Abuja.
- Òfin nìkan ló lè gbadé lórí àwa Ọba ìlú lbadan- Oba Lekan Balogun
- Aṣojú Seyí Makinde lásan ní mo jẹ, òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún mi - Ọ̀dọ́mọdé Kọmísánà
- Biodun Fatoyinbo fi ipò sílẹ̀ lorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀
- COZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo
- PFN: Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwádìí wa kò ṣe parí
Ó ṣeeṣe kí Fatiyinbo pẹ́ díẹ̀ ní ibá ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí lágọ̀ọ́ ọlọpàá nítori irú ìfọ̀rọ̀wánilẹ̀núwò yìí gba àwọn Dakólò ní wákàti mẹ́jọ gbáko kí wọ́n to pari.
Èyí wáyé lẹ́yin ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó Fatoyinbo ti kọ̀ láti fóju han ní àgọ́ ọlọpaàá lẹ́yìn ti wan ránṣẹ́ pèé fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Bakan náà ní ẹgbẹ́ tó n ri sí ìjọ ìgbàlóde (PFN) sọ lọ́sẹ̀ tó kọ́ja pé ó kọ̀ láti yoju sí ìpáde ti àwọn pèé sí fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.








