Shehu Sani: Buhari yẹ kó foyè dá àwọn akọni tókù lọ́lá pẹ̀lú

Oríṣun àwòrán, Sheu Sani /twitter
Senetọ Shehu Sani ti kede pe o yẹ kí ààrẹ Muhammadu Buhari bẹ idile àwọn ogoni to sọ ẹ̀mí wọn nu wò.
O mẹnuba awọn bii Ken Saro Wiwa, Sheu Musa Yaradua, Bẹẹkọ Kuti, àti Chinma Ubani nítorí àwọn náà kú fún ìjọba awa-ara-wa.
Senetọ Sheu Sani, tó n sojú ẹkùn aarin gbùngbùn Kaduna, ló kàn sí ààrẹ Buhari bẹ́ẹ̀ lórí ìkànni Twitter rẹ.
O ni pé, ìdílé Gani Fawehinmi àti MKO Abiola nìkan kọ́ lo kú fún ìjọba àwa-ara-wa, atí wipe ó pọn dandan lati bẹ ìdílé awọn akọni fun ijọba tiwantiwa yooku wo pẹ̀lú ìfàmì ẹ̀yẹ̀ dawọn lọ́lá.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Sẹnetọ Sani pe awọn ìdílé àwọn ènìyàn wọ̀nyìí pẹ̀lú nílo ìwúrí láti ọ̀dọ̀ ìjọba.










