World Cup 2018: Orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-àn ló ti gba ife sẹ́yìn

Ife ẹyẹ agbaye

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ohun ti gbogbo agbabọọlu agbaye n ja si ree!!!!!

Àjọ eléré bọ́ọ́lù lágbàáyé, FIFA, ló ń ṣe agbátẹrù ife ẹ̀yẹ àgbáyé, Ọdún mẹ́rin-mẹ́rin sì ni ìdíje naa máa ń wáyé.

Ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé jẹ́ ìdíje láàrin àwọn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù ọkùnrin láwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé.

Amin iyasọtọ kan
Uruguay ń gba ife ẹ̀yẹ akọ́kọ́ lágbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Uruguay àti Argentina kojú ara wọn lọ́dún 1930 amọ́ Uruguay ni orílẹ̀èdè àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ gba ife ẹ̀yẹ

Orílẹ̀-èdè Uruguay ló kọ́kọ́ gba àlejò ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé lọ́dún 1930, orílẹ̀-èdè mẹ́tàlá sì ló kópa nínú rẹ̀.

Agbábọ́ọ́lù West Germany méjì gbé ife ẹ̀ye lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orílẹ̀-èdè West Germany ló gba ife ẹ̀yẹ lọ́dún 1954, 1974 ati 1990

Ọdún 1942 si 1946 nìkan sì ni ìdíje náà kò leè wáyé nítorí ogun àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́ nígbà náà.

Àkọlé fídíò, Fídíò BBC yọ àwọn èèyàn FIFA níṣẹ́ ṣááju Russia 2018

Ìgbà ogún ni ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ti wáyé sẹ́yìn. Ìdíje ti ọdún 2018 sì ni yóò sọ ọ di mọ́kànlélógún, èyí tó ń wáyé lọwọ ní orílẹ̀-èdè Russia loṣù kẹfà si oṣù keje, ọdún 2018 bayii, nibi tí àwọn orílẹ̀-èdè bíi mẹ́tàlélógún sì ti n kópa nínú rẹ̀, ó kéré tán, ní ẹ̀ẹ̀kan soso.

Ikọ̀ agbábọ́ọ́lù Brazil sì gba ife ẹ̀yẹ lọdun1994

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Brazil gba ife ẹ̀yẹ lọ́dún 1958, 1962, 1970, 1994 ati ni 2002 fún ìgbà karun-un

Táa bá sì ní ká kàá ní ení, èjì, ọdún kejìdínláàádọ́rùn-ún rèé tí wọn bẹ̀rẹ̀ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé.

Àwọn agbábọ́ọ́lù England pẹ̀lú ife ẹ̀yẹ lọ́dún 1966

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lọ́dún 1966, England àti West Germany ló díje, England ni ife já mọ́ lọ́wọ́

Ikọ̀ agbábọ́ọ́lù láti orílẹ̀-èdè méjìlá ló ti dé ìpele àsekágbá ìdíje náà láti ìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ́lù méjọ péré ló tii gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé náà.

Ife ẹ̀yẹ àgbáyé lọ́dún 1986 táwọn agbábọ́ọ́lù ń pé wò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orílẹ̀-èdè Argentina sì ló gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé lọ́dún 1978 ati 1986 fún ìgbà keji

Orílẹ̀-èdè Brazil ló tíì se àseyọrí nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé jùlọ, tó sì jẹ pé òun náà sì ló tíì farahàn jùlọ nínú gbogbo ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ti ń wáyé.

Àwọn agbábọ́ọ́lù orílẹ̀èdè France gbé ife ẹ̀yẹ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lọ́dún 1998, France àti Brazil ni wọ́n figa-gbága àmọ́ France ló gba ife ẹ̀yẹ

Ọjọ́ Àìkú, ni àsekágbá àwọn ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé máa ń wáyé àyàfi ọdún 1930 àti 1966 nìkan tí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé wáyé ní ọjọ́rú àti ọjọ́ àbámẹ́ta.

Fabio Cannavaro, Balogun ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Spain n fẹnu ko ife ẹ̀yẹ lẹ́nu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lọ́dún 2010, Spain àti Netherland dije fún àsekágbá, Spain ló gba ife ẹ̀yẹ

Titi di ọdún 2014, àwọn orílẹ̀-èdè láti ilẹ̀ Europe àti South Amẹrika ni wọ́n ń figa-gbága nínú àsekágbá ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé.

Àwọn agbábọ́ọ́lù Germany pẹ̀lú ife ẹ̀yẹ lọ́dún 2014

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní 2014, Germany àti Argentina ni wọ́n tún náa tán bíi owó ní àsekágbá, tí Germany sì gbé ife ẹ̀yẹ lọ

Ẹlẹẹkọkanlelogun ni eyi to n waye lọwọ ni RUSSIA.

ife eye agbaye

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idije ife ẹyẹ agbaye ti di ajanaku kọja mo ri nkan fìrí bayii

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Àwọn Alex Iwobi kékèké
Àkọlé fídíò, Ọrọ ìfẹ́: Tunrayọ Adeoye kú lọ́sẹ̀ karun ti a sin ọkọ rẹ̀