June 12: Ó yẹ MKO Abiọla, ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, wo àwọn ǹkan tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ìsàmì rẹ̀ sẹ́yìn

Àwọn àwòrán yìí ló ń sàlàyé bí ayẹyẹ June 12 lọ́dún 2018 se dùn, tó lárinrin sí ní ìlú Abuja, Eko àti Ibadan.

Babatunde Fasọla ń kí Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Soyinka káábọ̀
Àkọlé àwòrán, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Soyinka ní ẹlẹ́nu méjì ni Muhammadu Buhari
Oju orori MKO Abiọla
Àkọlé àwòrán, Bi a ba ku laa dere, eeyan kii sunwọn laaye.
Buhari ń fún Kọla Abiọla ní ìwe ẹrí àmì ẹ̀yẹ GCFR

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Presidency

Àkọlé àwòrán, Àrẹ̀mọ olóògbé MKO Abiọ̀la, Kọla, gba àmì ẹ̀yẹ ní orúkọ gbogbo ẹbí Abiọla
Oloye MKO AbiọlaAbiola

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Abiọla kú ní ọjọ kèje osù keje, ọdún 1998 lẹ́yìn ìdìbò sípò ààrẹ ti gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé òun ló jáwé olúbori
Ìwé ẹ̀rí tí wọn fún Abiọla

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Presidency

Àkọlé àwòrán, M.K.O Abiola lo àkọlé 'Ìrètí fún ìpolongo ìdìbò lọ́dún 1993 èyí ti ààrẹ àna orílẹ̀-èdè Amẹríkà Barrack Obama náà mú lò ní ọdún 2008.
Babagana Kingibe, MKO Abiola àti Gani Fawẹhinmi

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Presidency

Àkọlé àwòrán, M.K.O Abiọla kú fún June 12 sùgbọn kìí ṣe òun nikan ló kú, ọ̀gágùn Sani Abacha náà kú ikú tó ya ni lẹ́nu ni June 8, 1998.
Alhaji Bola Ahmed Tinubu ń bá Kọla Abiọla sọ̀rọ̀ nìgbà tí olóyè Bisi Akande n wòran
Àkọlé àwòrán, Abiọla jẹ́ bàbá fún ọmọ tó tó ogójì, tó sì ní ìyàwó mẹrin.
Àwọn àwòrán MKO Abiọ̀la
Àkọlé àwòrán, Ní ọdún 1994, Abiọla kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúbori ninu ìdìbò ààrẹ ọdún 1993 ní ìlú Ẹ̀pẹ́tẹ̀dó ní ìpínlẹ̀ Èkó
Ọ̀pọ̀ èèyàn ní ib ìdálọ́lá MKO Abiọla

Oríṣun àwòrán, Twitter/Lagos State Goverment

Àkọlé àwòrán, Abiọla ni ọmọ kẹtalélogun fún bàbá rẹ̀.
Awọn ero to wa fun ayajọ June 12
Àkọlé àwòrán, Ile Abiọla kun pitimu fun ero lati se ayajọ June 12
Iwe ikede fun ayẹ́yẹ́ June 12
Àkọlé àwòrán, Ọdọọdun ni awọn ajafẹtọ ẹni maa n se iranti MKO Abiọla
Awọn ero ni ile Abiọla ni ilu Eko
Àkọlé àwòrán, Ero ko gbẹsẹ ni ile Abiọla fun ayajọ June 12
Iboji MKO Abiọla
Àkọlé àwòrán, Haa, ilẹ n jẹ eeyan. Ibi ti Abiọla sun si ree
Awọn ero to n se iwọde lati ranti Abiọla
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan lo ayajọ isinmi June 12 lati yẹ́ MKO Abiọla si
Awọn eeyan to n wọde lati yẹ Abiọla si
Àkọlé àwòrán, Bi onirese Abiọla ko tilẹ fin igba mọ, sibẹ eyi to ti fin ko lee parun
Awọn ero to n se iwọde lati ranti Abiọla
Àkọlé àwòrán, Ẹni ti araye n fẹ ni MKO Abiọla, ko ni arun kankan lara
Awọn ero ni ibudo akọroyin ni ilu Ibadan
Àkọlé àwòrán, Awọn akọroyin atawọn ajaftọ ẹ́ni ni ilu Ibadan naa fi aaye silẹ láti ranti MKO Abiọla
Awọn ero to wa fun ayajọ June 12
Àkọlé àwòrán, Ọrọ bọ ni ayajọ June 12 nilu Ibadan