June 12: Buhari foyè dá Abiọla, Fawẹ́hinmi lọla

Oloye MKO Abiola

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Buhari fún MKO Abiọla to kú ni ọdún 1998 layajọ ọjọ òṣèlú tuntun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ìjọba àpapọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà ti kéde ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹfa (June 12) gẹ́gẹ́ bíi àyájọ ọjọ́ iṣèjọba awa-ara-wa dipo ọjọ́ kọkandinlọgbọn, osu karun-un (May 29) to maa ń wáyé l'ọdọọdun.

Ààrẹ Muhammadu Buhari kéde rẹ lẹ́yin ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèkan lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà ní wọ́n fẹnukò pé láti àsìkò yìí lọ June 12 yoo máá jẹ àyájọ ọjọ́ náà.

Ìjọba ṣe èyí láti bu ọlá fún ògúna gbòǹgbò ọmọ Yorùba MKO Abiola to kú ni ọdún 1998.

Eyi tumọ si pe, ohun ti MKO Abiọla ko gba loju aye rẹ n ṣẹlẹ lẹyin rẹ ti wọn fi fi oyè to tobi julọ da òkú rẹ lọla bayii.

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìjọba àpapọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà ti kéde ọjọ́ kejìlá oṣù kẹfa gẹ́gẹ́ bíi àyájọ ọjọ́ iṣèjọba awa ara wa

Bákan náà ní wọn pinnu láti fun Abiola ni oye GCFR, Gani fawehinmi àti Baba Gana- Kingibe ni GCON, tí wọn sì fí àyẹyẹ náà sí ọjọ́ kejìlá ,oṣù kẹfa yìí.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Lori awọn opo ikansira ẹni lori ayelujara, ọpọ eeyan lo ti n sọ ero wọ́n nipa ikede yii. Ni oju opo Twitter, ilẹ́ ti we

Temilade @Temilade ni a bẹ Ọbasanjọ titi pe ko sọ ọjọ ijọba tiwa n tiwa di June 12, o kọ jalẹ. Ohun taa ni ko se wa ni ẹ́ya Fulani se yii..

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Reuben Abati ni igbesẹ to yaayi gbaa ni eyi amọ se lo yẹ ki wọ́n kede Basọrun MKO Abiola gẹgẹ bii ẹni to bori ninu idibo June 12

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Femi Adebayo: Ẹyin ọ̀dọ́, ẹ káàbọ̀ ságbo ilé Tíátà