Ibrahim Attahiru: Àjọṣepọ̀ wò ló wà láàrin ọgagun tuntun Attahiru, Buratai àti Shekau?

Ọgagun Attahiru

Oríṣun àwòrán, AFP

Lara awọn ọgagun ileeṣẹ ologun Naijiria tuntun ti aarẹ Buhari yan sipo, ọkan wa lara wọn tawọn eeyan n ran ọrọ rẹ lẹnu.

Ẹni taa n wi yi ni ọgagun Ibrahim Attahiru.

Ṣaaju iyansipo rẹ, oun ni adari ikọ ọwọ keji ọmọ ogun ilẹ wa (82 Division) ni ileeṣẹ ologun Naijiria.

Amọ loju opo ayelujara, awọn eeyan ko dakẹ lori ọrọ rẹ paapa ibaṣepọ ati ohun to ti waye sẹyin laarin rẹ ati ọga to gba ipo lọwọ rẹ Tukur Buratai.

Nkan marun un ree to yẹ ki o mọ nipa Attahiru:

Oun ni asaaju ikọ ologun Operation Lafia Dole:

Lọdun 2017 wọn yan sipo lati koju ikọ Boko Haram gẹgẹ bi adari Operation Lafiya Dole, ti wọn fi n gbogun ti ikọ mujẹ mujẹ Boko Haram.

''Ri wi pe o mu oku tabi aaye Shekau wa laarin ogoji ọjọ''

Aṣẹ yii ni ọgagun Tukur Buratai pa fun ọgagun Attahiru ni ọdun 2017 to yan an sipo adari ikọ idoju ija kọ Boko Haram naa.

Awọn ologun joko sori ilẹ

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Awọn ologun ti kọkọ se eto abo kogberegbe Python dance ati Crocodile Smiles

Iyansipo yii ko so eso rere fun Attahiru nitori asiko to gba iṣẹ yi ni Boko Haram wa bẹrẹ si ni sooro ju ti tẹlẹ lọ.

Lara awọn nkan ti Boko Haram da lara ni pe, wọn ṣigun lọ si olu ilu ipinlẹ Borno, Maiduguri.

Lasiko taa n wi yii, Boko Haram pa eeyan aadọta ni Mọṣalaṣi loṣu Kọkanla ọdun 2017.

Awọn Attahiru

Oríṣun àwòrán, State house

Losu Keje ọdun 2017 bakan naa ti Attahiru wa lori ipo, awọn eeyan to le ni ogoji padanu ẹmi wọn lasiko tawọn ọmọ ogun n gbiyanju lati doola awọn ti Boko Haram ji gbe.

Lara awọn to ba iṣẹlẹ yii lọ ni awọn ọmọ ogun ati awọn ikọ to n ṣe iwadi nipa pipọn epo rọbi lagbegbe Borno.

Aworan Buratai Attahiru ati Shekau

Ko tan sibẹ, iṣọwọ lo awọn to de ado oloro mọra ati yiyin ado oloro lu awọn ọmọ ogun lasiko ti Attahiru wa lori oye peleke si ju ti tẹlẹ lọ.

Eyi to jẹ pabanbari ọrọ yii ni pe, Attahiru ko ri olori ikọ agbesunmọmi Shekau mu titi ti gbedeke ti ọga rẹ Tukur Buratai fun fi pe.

Amọ awọn kan woye pe iṣẹ ti wọn gbe le lọwọ naa jẹ eyi ti yoo ṣoro lati ṣe nitori awọn to ṣaaju rẹ naa ko ri Shekau mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Abubakar Shekau

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọ ogun mẹjẹ lati orilẹẹde Naijiria ati Cameroon ni wọn padanu ẹmi wọn ninu ikọlu naa

Nicholas Rogers ni ọgagun to gba ipo naa lọwọ rẹ nigba ti wọn yọ kuro.

Ninu ọrọ idagbere rẹ, ọgagun Attahiru sọ pe awọn ribi pa awọn ọgagun Boko Haram marun un ati awọn ọmọ ogun rẹ aadọta .

Nigba ti wọn yọ kuro, ileeṣẹ ologun ko sọ idi ti wọn fi yọ sugbọn wọn gbe kuro lati lọ di ipo mii mu, ti wọn ko kọkọ sọ ipo to jẹ nigba naa.

Pẹlu ohun to ti waye sẹyin pẹlu ọgagun Attahiru, ọga rẹ tẹlẹ Tukur Buratai ati olori ikọ Boko Haram Abubakar Shekau, ibeere tawọn eeyan beere ni pe ṣe yoo ribi dẹkun Boko Haram?

Igba diẹ lo ku ti ijọba aarẹ Buhari yoo lo lori oye nitori naa awọn eeyan ti n sọ pe o le maa ribi ṣe iṣẹ daada depo pe yoo dẹkun Boko Haram.