Nigeria 2019 Election: Ilé iṣé ológun ní àwọn olóṣèlú kan fẹ́ yin àdó olóró lásìkò ìbò gómìnà

Oríṣun àwòrán, Nigerian army
Olori ile isẹ ologun oriilẹede Naijiria, Ọgagun agba Tukur Buratai sọ pe, iwadi awọn fihan pe awọn olosẹlu kan n gbero lati da rogbodiyan silẹ lasiko idibo gomina ọjọ Abamẹta.
Ọgagun Burutai ni awọn eeyan kan n gbero lati tajẹ silẹ, bẹẹ ni wọn si fẹ ju ado oloro lati da ibo iru lọjọ Satide.
Ṣugbọn Burutai ni ile iṣẹ ologun ko ni gba wọn laye lati mu ipinnu wọn ṣẹ.
Ọgagun BUrutai fọrọ yii lede nibi ipade to ṣe l'Abuja l'Ọjọru pẹlu awọn lọgalọga ninu iṣẹ ologun.
Burutai salaye pẹlu ẹdun ọkan pe, awọn ọmọgun mẹta ati oṣiṣẹ eleto idibo kan padanu ẹmi wọn lasiko ibo aarẹ lọjọ kẹtalelogun oṣu keji to lọ.
O fi asiko ipade naa kilọ fawọn ologun lati mase tẹle olosẹlu kankan lasiko idibo ṣugbọn ki wọn gbiyanju lati dẹkun iwa jagidijagan lasiko ibo.









