Buhari: Ìpèsè ààbò, ọrọ̀ ajé, iṣẹ́ òòjọ́, ohun èèlò ni yóò jẹ mí lógún

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Aarẹ orilẹede Naijira, Muhammadu Buhari ti jẹjẹ pe oun yoo sisẹ kara lati mọ le awọn aseyọri oun ni saa isejọba oun akọkọ.

Buhari ni awọn ẹka ti oun ko ti ni tẹti ni ipese eto aabo to yanranti, ọrọ aje to duro re, ipese isẹ oojọ, igbogun tiwa ajẹbanu ati ipese awọn ohuneelo amayedẹrun to duro re.

Aarẹ Buhari jẹjẹ yii lasiko to n gbalejo awọn asaaju ẹgbẹ Arẹwa to wa se ẹ ku oriire si nile ijọba nilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ Buhari ni oun ko ni ja awọn ọmọ Naijiria to ni igbẹkẹle ninu oun kulẹ ni saa keji yii pẹlu afikun pe gbogbo ipa ni oun yoo sa lati tẹ awọn araalu lọrun.

Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori eto irofin, Garba Shehu fisita ni aarẹ wa dupẹ pupọ lọwọ awọn agbaagba Arẹwa fun apọnle ti wọn fun oun ati atilẹyin wọn.

"Igbesẹ to kẹyin fun mi ni eyi jẹ. Ma sa gbogbo ipa mi lati sisẹ kara ju bi mo ti se tẹlẹ lọ, ti n ko si ni ja yin kulẹ rara."

Buhari ati awọn ọba

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Àwọn lọbalọba labẹ ẹgbẹ National Council of Traditional Rulers lọ kí Ààrẹ ní Abuja lẹ́yìn tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sípò Ààrẹ.

Ẹ̀yin ọba alayé ló mọ ọ̀daràn, ẹ ti mí lẹ́yìn láti wá wọn rí - Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kesi awọn ọba lorilẹede Naijiria lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari sọ eyi lasiko to n gbalejo awọn ọba ni ile aarẹ ni ilu Abuja, lasiko to n ki wọn kaabọ si saa keji rẹ gẹgẹbi aarẹ orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde: Màá fẹ́ káwọn aráàlú mọ ìpa ìjọba mi lára sí rere

O fikun wi pe, oun yoo pada si ile oun ni Daura ni ipinlẹ Katsina lẹyin saa keji oun gẹgẹ bi aarẹ.

Buhari ati awọn ọba

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aarẹ orilẹede Naijiria ni, lọpọ igba awọn ọba mọ awọn idile ti awọn ọdaran wa, nitori naa ni wọn se nilo awọn ọba ti wọn yoo soju awọn eniyan lọna to lamilaaka.

Buhari ati awọn ọba

Oríṣun àwòrán, Twitter

Sultan ti ilu Sokoto, Alhaji Muhammad Sa'ad Abubakar III lo saaju awọn ọba naa lọ si ile aarẹ.