Lockdown school feeding programme: To bá ní ọmọ ni kíláàsì Kínní dé ìkẹta nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tìjọba, lọ gba oúnjẹ fún ọmọ rẹ - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Humanitarian Affairs
Ijọba apapọ ti kede pe Ọjọbọ ọla ni eto ipese ounjẹ fawọn akẹkọọ jakejado Naijiria yoo bẹrẹ nilu Abuja, Eko ati Ogun.
Ileesẹ to wa fun ipese ohun iranwọ nilẹ wa lo sisọ loju ọrọ yii ninu atẹjade kan tó fisita loju opo Twitter rẹ.
- Nínú ìṣèjọba yìí, Èmi àti Ààrẹ Buhari lọlọ́rọ̀, kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà-Ibrahim Gambari, olórí òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì ààrẹ
- Aláàfin gbé àṣẹ kalẹ̀ láti dènà àtúnṣẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ 'Soka'nílùú Ọ̀yọ̀
- Mo kábàámọ̀ pé n kò kàwé, kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà - Sanyeri
- Ìdí táwọn apòògùn Nàìjíríà fi tako oògùn Coronavirus láti Madagascar
Atẹjade naa ni gbogbo ipinlẹ tó wa ni Naijiria ni wọn ti rọ lati lo gbogbo akọsilẹ to wa nikawọ wọn lati tọ ipaṣẹ ilegbe awọn akẹkọọ to wa lawọn ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ijọba.
Ṣugbọn yatọ si bo ṣe n waye tẹlẹ, ijọba ni awọn obi ati alagbatọọ awọn akẹkọọ to lẹtọ si ounjẹ ijọba naa, ni wọn yoo gbe fun.
"Kikida awọn akẹkọọ to wa ni kilaasi kinni si ikẹta lawọn ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ijọba nìkan, ni yoo jẹ anfaani ipese ounjẹ naa, eyi ti yoo kan ojule biliọnu mẹta o le diẹ, 3,131,971."

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Humanitarian Affairs
Lara awọn eroja ounjẹ ti ijọba yoo pin fun idile akẹkọọ kọọkan to lẹtọọ si ounjẹ naa ni, apo irẹsi oni kilogiramu marun-un (5kg), apo ẹwa oni kilogiramu marun-un bakan naa, ororo ẹẹdẹgbẹta mililita, 500ml, epo Pupa oni ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwaa mililita, 750ml, iyọ oni ẹẹdẹgbẹta miligiramu, 500mg, ẹyin ẹyọ mẹẹdogun ati tomato lílọ lubu-lubu oni miligiramu ogoje, 140gm.
Ijọba ni apapọ gbogbo owo awọn eroja ti wọn fẹ pin fun awọn obi akẹkọọ to lẹtọọ si ounjẹ naa, jẹ ẹgbẹrun mẹrin ati igba Naira, N4,200.

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Humanitarian Affairs
Ijọba apapọ tun ni ilana tawọn fẹ lo yii, ni yoo jẹ ko rọrun lati ri awọn akẹkọọ naa fun ni ounjẹ lasiko yii ti gbogbo ile ẹkọ wa ni titi pa nitori igbele arun Coronavirus.
"Igbesẹ pinpin iwe ẹtọ si ounjẹ naa, ta pe ni Voucher ti n waye lọwọ nilu Abuja ati Eko, ti ijọba si ti n pese owo fun awọn ijọba ipinlẹ lati seto ipese ounjẹ fun akẹkọọ nipinlẹ koowa wọn."
Czech Republic: Takọ-tabo Kìnìún ni ọkùnrin náà ń sìn nínú àgò kanṣoṣo

Oríṣun àwòrán, ZDENEK NEMEC/MAFRA/PROFIMEDIA
Atẹjade naa ni lati ojule de ojule ni wọn yoo pin 'voucher' naa, eyi ti yoo ni sitampu, ọjọ ati akoko ti gbigba ounjẹ yoo kan ile kọọkan, ti wọn yoo si loo lati gba ounjẹ ni ibudo ti wọn ti n pin ounjẹ naa.
Michal Prasek ni olóńgbò nla, eyiun kiniun to ti n sin fun ọdún mẹ́sàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aládugbò n ké gbàjarè lórí ọ̀rọ̀ náà tẹ́lẹ̀.
Bàbá Prasek yii lo sadede ri òkú ọmọ rẹ̀ nínú ilé kìnìún, to sí ké sí àwọn akọròyìn abẹ́le lati kede ohun to ṣélẹ̀ àti pé, ilẹkùn ilé kìnìún náà wà ni títì sínú.
Awọn ọlọpàá ti wọn pè wá wo ohun to ṣẹlẹ̀, kọ́kọ́ pa awọn ẹranko míràn to wà nínú àgò tó fara ti kìnìún náà.
- NFF fi #30,000 kún #10,000 owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini àti Samuel Okwaraji
- Thai king: Ọ̀nà wo ní ẹ̀ṣọ́ ọba gbà di olorì láàfin?
- Coronavirus: Ǹjẹ́ àwọn dókítà tó ń tọ́jú eyín ń ṣisẹ́ lásìkò pàjáwìrì? Àti àwọn ìbéèrè míràn
- Lóòtọ́ lò n lo ìbomú-bẹnu, ṣùgbọ́n ṣe bóṣeyẹ kí o wọ̀ ọ́ ló ṣe n ṣe?
Agbẹ́nusọ ọlọpàá ní, pípa ti wọn pa àwọn ẹranko tó ku náà ṣe pàtàkì láti le kọja sọ́dọ̀ ẹni ti kìnìún pa.
Ọgbẹ́ni Prasek, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ra kìnìún lọ́dún 2016, o tún wa ra abo ni ọdun to kọja, to si kó àwọn méjèèjì pọ̀ sinu àgò kannáà lẹ́yìnkùlé rẹ ni abúle Zdechov.
Sáájú ní ìjọba ti kọ láti fun láàyè láti kọ́lé fún pé, ó ń sí eranko lọ́nà àìtọ́, sùgbọ́n èdè àìyedè bẹ́ sílẹ̀ nígbà to kọ̀ láti jẹ́ ki àwọn aláṣẹ̀ wọ inú ọgbà rẹ.
Sugbọn wahala bẹ silẹ nigba ti ẹnikan to n wa kẹkẹ sadede kọlu abo kiniun rẹ lasiko to n mu gba atẹgun lọ loju popo, to si fi okun si lọrun bii aja.
Nibayii, kiniun to n sin naa, lo papa ran an sọrun ọsan gangan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Seyi Makinde làwa ń bá lọ lọ́jọ́ Satide - Ladọja
- Bí mo ṣe ń tako Buhari bá ìjọba tiwantiwa mu - Ọbasanjọ
- Ìbò sáà kẹta fún Ajimọbi ni ìbò Adelabu, ẹ yàgò fun - Seyi Makinde
- Níbo lowó ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ wa wà - Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kwara ń bèèrè?
- Ọbasanjọ ni ọmọ òrùkàn tó di olóri orílẹ̀èdè lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
- Ọbasanjọ sọ àsírí sàgbàdèwe rẹ̀













