Ash Wednesday: Ọjọ́ eérú ń rán wa létí eérú fún eérú, erùpẹ̀ fún erùpẹ̀

Ẹnikan to se ami sori pẹlu eeru

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdọọdun ni awọn ọmọlẹyin Kristi ma n se ayẹyẹ Ọjọ Eerú to jẹ ọjọ kẹrindinlaadọrin saaju ọdun Ajinde.

Ọjọ Eeru yii ni wọn fi n bẹrẹ isera ati aawẹ fun ọdun Ajinde ti awọn onigbagbọ, to tumọ si iku ati Ajinde Jesu Kristi.

Lasiko Ọjọ Ẹẹru naa, to maa n waye ni Osu Keji tabi Osu Kẹta ni ọdọọdun, la maa ri awọn eniyan ti wọn yoo ma n rin kaakiri pẹlu ami agbelebu ti wọn fi eeru kọ siwaju ori wọn.

Awọn ọmọlẹyin Kristi gbagbọ wi pe, asiko aawẹ fun ogoji ọjọ yii safihan asiko ti Jesu Kristi fi wa ninu aginju pẹlu aawẹ ati adura, ki satani to wa dan wo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn onigbagbọ maa n lo asiko naa lati gbadura, ati lati kọ ẹkọ nipa igbe aye Jesu Kristi, iku rẹ, isẹ rẹ loke erupẹ, ati ajinde rẹ kuro ninu oku.

Ki ni pataki Ọjọ Eeru ninu Igbeaye awọn Onigbagbọ?

Ọjọ eeru to wọpọ laaarin awọn onigbagbọ ti Ijọ Aguda, Ijọ Anglican, Methodist ati awọn Ijọ igbalode miran.

Ni ọpọlọpọ awọn ijọ onigbagbọ, wọn ma n lo eeru ti wọn jo ku lara imọ ọpe ti wọn lo fun ọdun Ọjọ imọọpe (Palm Sunday), to waye ni ọdun to kọja.

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde: Màá fẹ́ káwọn aráàlú mọ ìpa ìjọba mi lára sí rere

Ọpọlọpọ awọn oluso agutan ati pasito ma n lo ọjọ naa lati fi se iwaasu to ba asiko naa mu.

Eeru ti ayajọ ọjọ yii se apejuwe iku ati ironupiwada eleyii ti awọn adari ijọ ma n fi si awọn ara ilu lori, pẹlu ọrọ wi pe' éeru fun eeru, iyẹpẹ ni wa, ati wi pe ilẹ la o padasi.

Bakan naa ni wọn gbagbọ wi pe ti awọn onigbagbọ ba se n gba ami agbelebu yii sori, wọn n jẹwọ ẹsẹ wọn fun Ọlọrun.

Àkọlé fídíò, Yeyeluwa Ibiyemi Ajadi

Ọjọ Kejilelogun, oṣu keji ni Ọjọ Eeru ti ọdun yi waye, nigba ti awọn ọjọ miran to so mọ ọjọ eeru bii ọjọ ti Jesu wọ Jerusalem pẹlu ariwo ayọ ti yoo waye ni laipẹ.

Ọjọ Iwẹsẹ yoo waye, bakan naa ni Ọjọ Friday rere yoo waye ni kete ti aawẹ ba ti pari ati Ọjọ Ajinde Kristi yoo waye lẹyin rẹ.

Àkọlé fídíò, Mother tongue day 2021, Akomolede, YSAN: A ti parí iṣẹ́ lórí èdè ìperí Meta-Language Yorùb

Awọn ohun mẹta to jẹ eewọ Ọjọ́ Eérú

  • Awọn ọmọ ijọ Aguda to ti pe ọmọ ọdun mẹrinla ko gbọdọ ge ẹran ni ọjọ naa.
  • Eeru ti wọn lo fun Ọjọ̀ Isinmi Ọpẹ ni ọdun to kọja ni wọn ma n tun lo.
  • Ẹ ko gbọdọ ki eniyan ku ‘ọdun Ọjọ Eeru’
  • Ọmọlẹyin Kristi ko gbọdọ jẹ ẹran to ni ẹjẹ lọjọ eeru