Sunday Igboho: Òfin kóńlé-ó-gbélé gbòde n'Ibarapa lórí ẹ̀rù pé Fulani le k'ógun wá lẹ́yìn àbẹ̀wò Igboho

Ibẹru-bojo gbalẹ niluu Igangan lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo lẹyin ikọlu to waye laarin ajijagbara Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho atawọn Fulani lagbegbe ọhun.
Koda awọn olori agbegbe naa ti kede ofin konle-o-gbele lati aṣaalẹ ti idaji aarọ.
Eyi wa lara awọn igbesẹ lati dena awọn Fulani to le fẹ pada wa gbẹsan lẹyin ti ikọlu pẹlu Igboho.
- Èèyàn mẹ́tàdínlógún(17) jọ́ná ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì lópòpóónà Bode-Saadu sí Jebba
- Ta bá gba Seriki Fulani padà sí Igangan, a fi ọwọ́ ara wa, pa ara wa ni - Aráàlú
- Ẹ yé ṣí ìhòhò ara yín síta lórí ayélujára torí ‘Silhouette Challenge’ - Adeboye
- Seyi Makinde, Akeredolu, òfo ni kùrù-kẹrẹ yín lọ́dọ̀ Buhari lórí ìpèsè ààbò - Falana
- Wo àwọn ọmọ Yorùbá tó ń ti Sunday Igboho lẹ́yìn bí i iké
- Ẹ múra mi sílẹ̀ ẹ̀yin apààyàn Fulani ní Ogun, mò ń bọ̀ kánkán - Sunday Igboho
- Àwọn olóṣèlú ti ń fowó bẹ̀ mí kí n má bá Fulani jà torí ìbò 2023, àmọ́ o ti bọ́ - Sunday Igboho
Ti ẹ ko ba gbagbe, Igboho pẹlu ero lẹyin yabo ibugbe awọn Fulani niluu Igangan lẹyin to fun wọn lọjọ meje lati fi Ibarapa silẹ.
Lati igba naa lẹru ti n bawọn ara ilu Igangan pe awọn Fulani le gbeja wa ko wọn.
Awọn eeyan agbegbe naa kepe ijọba lati ṣe iwadii Seriki Fulani ipinlẹ Oyo, Abdulkadir Saliu lori ẹsun ijinigbe atawọn ẹsun iwa ọdaran mii ti wọn fi kan an
Oludasilẹ ẹgbẹ to n ri si idagbasoke ile Igangan, Ọgbẹni Oladokun Oladiran sọ fawọn akọroyin pe awọn eeyan agbegbe naa ṣe ofin konle-o-gbele nitori awọn ko ni igbagbọ ninu eto abo ti ijọba pese fawọn.

Ọgbẹni Oladiran ṣalaye pe awọn ko ti ri awọn ẹṣọ Amotekun igba ti Gomina Seyi Makinde kede pe oun ti ran si agbegbe naa.
O rọ Makinde pe ki o ṣe abẹwo si agbegbe Ibarapa lati fi oju ara rẹ ri ohun to n ṣẹlẹ gan an nibẹ pẹlu awọn Fulani darandran.
Ọgbẹni Oladiran ṣalaye siwaju sii pe awọn Fulani si wa lawọn agbegbe bii Ile Bamogba ati AUD niluu Igangan lai si wahala kankan.
''Ṣugbọn ohun tawọn eeyan ilu Igangan ko fẹ ni awọn Fulani kan to n huwa ọdaran.














