Pavillion Hotel: Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni ilé ìtura ọ̀hún láti wá sọ tẹnu rẹ̀ lórí kámẹ́rà tó wà nínú yàrá

ile itura

Oríṣun àwòrán, others

Bi awuyewuye ti n lọ lori ile itura Pavillion Hotel suite to gbe ẹrọ kamẹra sinu awọn yara to wa ni ile itura naa, ileeṣẹ ọlọpaa ti ranṣẹ pe ẹni to ni ile itura naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko wa sọ tẹnu rẹ idi to ṣe fi kamẹra CCTV sinu yara tawọn alejo n gba.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ṣalaye pe ilu Eko ni ẹni to ni ile itura naa to wa ni Odogbolu n gbe.

Amọ, Ọgbẹni Oyeyemi sọ pe ọga DPO ilu Odogbolu ti sọ fun un pe ko wa sọ idi to ṣe fi kamẹra sinu yara tawọn eeyan n gba.

O ni iwadii si n lọ lọwọ lori ẹsun pe ile itura ọhun n ṣe ayọjuran si ohun tawọn alejo ba n ṣe ninu yara ti wọn ba gba.

ile itura

Oríṣun àwòrán, others

Ọrọ naa bẹrẹ nigba ti alejo kan nile itura naa fi fidio to ya nibẹ lede lori ayelujara ninu eyi to ti ṣalaye pe wọn fi CCTV sinu awọn yara to wa nibẹ eleyi to lodim sofin.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Ọkunrin naa sọ ninu fido ọhun pe ninu yara marun un lawọn ti ri iru kamẹra bẹẹ.

O ni awọn kamẹra yii ti maa ka ihoho burọda ati mama oun.

Ọrọ yii ti di iṣu ata yan-an yan-an lori ayelujara debi pe awọn ilumọọka naa da si ọrọ naa pe ileeṣẹ ọlọpaa ni lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.

Ó lódì sí òfin kí ilé ìtura fí 'camera' sí inú yàrá tí àwọn ènìyàn wà- Irukera FCCPC

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti ni o lodi si ofin ti awọn eniyan ma tẹlẹ aṣẹ to de asiri awọn eniyan.

Ọga Agba ileeṣẹ Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC), Babatunde Irukera lo sọ bẹẹ lasiko to n fesi si iṣẹlẹ bi ile itura kan ṣe fi ẹrọ amohunmaworan si inu awọn yara to wa ninu ile itura naa.

FCCPC

Oríṣun àwòrán, @FCCPC

Irukera ni awọn ọmọ Naijiria ni aṣẹ si aṣiri wọn (Privacy) ti ko si tọna ki ẹnikẹni tu aṣiri wọn sita.

Amọ, o fikun wi pe o ṣeeṣẹ ki o ni awọn igba kọọkan ti ijọba le tẹ oju ofin yii mọlẹ, amọ ijọba nikan lo laṣẹ lati ṣẹ bẹẹ.

Ọga Agba ileeṣẹ Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC), Babatunde Irukẹra fikun wi pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.

bbc

Saaju nigba ti a fi iroyin naa lede ni awọn eniyan ti ṣe lodi sii loju opo BBC Yoruba.

bbc

Koda, awọn ero ti sọ riṣiriṣi nipa eyi ni awọn oju opo ayelujara

ile itura

Oríṣun àwòrán, others

Ṣé o tọ̀nà kí ilé ìtura máa fi 'Camera' sí iyàrá ìbùsùn àwọn àlejò?

Njẹ o tọ ki ile itura fi ''camera'' si iyara ibusun awọn alejo?

Awọn alejo ile itura faraya nitori camera ti wọn ri ni iyara ibusun wọn

Ile itura kan ni ipinlẹ Ogun ti ko ibinu awọn alejo to wa sun nibẹ nitori bi wọn ti sefi ẹrọ ayaworan si inu iyara ibusun awọn alejo naa.

Ninu fọnran fidio kan ti a ri loju opo ayelujara ni akara ọrọ yi ti tu sepo.

A ko le fidi ọrọ naa mulẹ lori asiko ti wọn ya fọnran naa tabi ibi ti wọn ti ya fidio yi sugbọn pẹlu ohun ti awọn to wa ninu rẹ n sọ.

Nise ni awọn eeyan kan n faraya pẹlu bi ile itura yi ti se fi 'camera' pamọ sinu iyara wọn.

Àkọlé fídíò, Mckinley Erves di ẹni tọ ń ríran rí aàwọ̀ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀

Awọn kan n sọ pe ile itura ti wọn ti ya fidio yi wa ni Ayepe ni ijọba ibilẹ Odogbolu., ni ipinlẹ Ogun ni Guusu Iwọ oorun Naijiria.

Wọn ko kọ asiko ti wọn ya fidio naa tabi orukọ ẹni to ya a ki wọn to bẹrẹ si ni se alabapin rẹ kaakiri.

Kini kan to daju ninu fọnran naa ni pe awọn kan ti wọn jọ ẹni to ni ile itura yi n fidi rẹ mulẹ pe awọn lẹtọ lati fi fidio sinu iyara awọn alejo to wa sibẹ.

Koda, a gbọ ninu fidio naa nibi ti arakunrin kan (ẹni to seese ko ni ile itura naa) ti n sọ pe awọn lẹtọ lati fi ẹrọ kamẹra sinu iyara awọn alejo.

Ohun to fa ki awọn eeyan maa gba ọrọ inu fọnran yi bi ẹni gba igba ọti ni pe ọkan lara awọn alejo n faraya pe erọ kamẹra to wa ni ibusun awọn ko bikita asiri bibo fun awọn.

Àkọlé fídíò, Tolulope Adeleke Aire: Mo wòye pé àwọn ọkùnrin Nàìjíríà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ tu

Bi ọrọ yi ba fi le de iwaju adajọ, o seese ki wọn fi iya jẹ awọn ti ko bikita lati maa ya awọn eeyan laigba iyọnda lọdọ wọn.

Titi di bi ase n ko iroyin yi jọ, a ko ri akọsilẹ pe awọn to fi fidio yi sita ti fẹjọ sun awọn ọlọpaa.