Sunday Igboho: Ìjọba gbọ́dọ̀ fí òfin dé ìrìnàjò àwọn Fulani darandaran láti àríwá sí gúúsù Nàíjíríà

Gomina Abdullahi Ganduje

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ganduje

Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti ni ki ijọba orilẹ-ede Naijiria fi ofin de irinajo awọn Fulani darandaran ati ẹran wọn lati ariwa orilẹ-ede Naijiria lọ si ibo miran.

Gomina Ganduje lo fi ero rẹ han lori ọna abayọ si ija laarin awọn Fulani darandaran ati agbẹ lorilẹ-ede Naijiria ni Katsina.

Ipade naa waye laarin awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ati aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari.

Ganduje lasiko ti o n sọrọ ni o da oun loju wi pe fifi ofin de awọn Fulani darandaran lati ma ṣe rin irinajo wa si guusu Naijiria yoo fopin si ipaniyan ati ija laarin awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ.

Gomina Ganduje ni awọn ti kọ agbegbe, Ruga Settlement fun awọn darandaran ni agbegbe Samsosua, to jẹ aala laarin ibode ipinlẹ Kano ati ipinlẹ Katsina.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Ganduje ni:

'' A n kọ ile loriṣiriṣi, pẹlu adagun omi to fi mọ ojuko ti wọn ti n ṣetọju awọn maalu''

Ija laarin awọn Fulani darandaran ati agbẹ ti da ọpọlọpọ rogbodiyan silẹ, to si doju eto aabo orilẹede Naijiria bolẹ.

Ọpọlọpọ igba ni awọn agbẹ ti fi ẹsun ipaniyan, ijinigbe ati awọn iwa ọdaran miran ati biba ohun ọgbin awọn agbẹ jẹ.

Ọrọ naa ti fa yanpọn-yanrin laarin wọn to fi mọ ija laarin eekan ni ilẹ Yoruba , Sunday Igbohọ ati awọn Fulani darandaran ni agbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Lawal Ayankemi Oluwatoyin: Mo kọ̀ láti máa tọrọ owó nítorí ojú mi tó fọ́, iṣẹ́ ló wù mí

Eyi ti mu ki awọn gomina ni iwọ oorun Guusu Naijiria ṣe ipade ti wọn si fofin de dida ẹran kaakiri ni awọn ipinlẹ, to fi mọ dida ẹran ni alẹ.

Ti a ko ba gbagbe, ni opin oṣẹ ni awọn afurasi darandaran ṣe ikọlu si awọn oloko ni agbegbe Ibarapa ati Oke Ogun ni ipinlẹ Oyo.