Driving offence: Àjọ FRSC kìlọ̀ f'áwọn awakọ̀ tó máa tẹ fóònù lórí ìrin ní ìpínlẹ̀ Eko.

FRSC

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ajọ ẹṣọ oju popo ti kilọ fawọn awakọ to maa n tẹ foonu lori irin nipinlẹ Eko pe ki wọn so ewe agbejẹ mọwọ.

Ọga ajọ FRSC nipinlẹ Eko, CC Olusegun Ogungbemide lo sọrọ ikilọ yii ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita lọjọ Aiku.

Ogungbemide ni gbogbo awọn ẹṣọ lo ti wa lojufo bayii lati maa mu ẹnikẹni ti aje iru iwa ba ṣi mọ lori.

Ọga ajọ FRSC ni awọn ẹṣọ oju popo ko le laju silẹ ki wọn maa wo awọn to n tapa si ofin ọkọ wiwa popo ki wọn maa ṣe ohun to lodi sofin.

''Gbogbo awakọ ni ofin oju popo wa fun, eyi lo yẹ ki wọn ṣe awọn nkan ti ko le ge ẹmi wọn kuru lojiji,'' Ogungbemide ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Lawal Ayankemi Oluwatoyin: Mo kọ̀ láti máa tọrọ owó nítorí ojú mi tó fọ́, iṣẹ́ ló wù mí

Ọga ajọ FRSC nipinlẹ Eko ṣalaye pe o wa ninu ofin irina pe awakọ kankan ko gbọdọ lo foonu lọna kọna nigba ti o ba wa lori irin.

O ni bakan naa ni ofin ọhun tun sọ pe olukọni ni ọkọ wiwa gan an ko gbọdọ pe ẹnikẹni lori foonu tabi gba ipe.

Àkọlé fídíò, Pangolin Covid-19: Ẹ wo ẹranko tó ṣeéṣe kó ní ǹkan ṣe pẹ̀lú à[rùn Coronavirus!

Ogungbemide ni awọn ofin naa ree lẹyọkọọkan:

  • Ofin ko faaye gba fifi ranṣẹ tabi gbigba atẹjiṣẹ ti o ba n wakọ
  • O kọ gbọdọ fi iwe ranṣẹ tabi gba iwe ti o ba n wakọ
  • O ko gbọdọ gba aworan tabi fọto ti o ba n wakọ
  • O ko gbọdọ lo ẹrọ ayelujara ti o ba n wakọ

Ọga ajọ FRSC nipinlẹ Eko ṣalaye pe fun anfaani ''ara wa ni gbogbo awọn ofin yii wa fun.''

Ogungbemide ni ọpọ awakọ lo ṣagbako iku ojiji lori titẹ foonu nigba ti wọn n wakọ.

Àkọlé fídíò, Mckinley Erves di ẹni tọ ń ríran rí aàwọ̀ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀