2020 Budget: ₦75m nìjọba yóò fi ra epo àti àtúnṣe ẹ̀rọ amúnáwá níléeṣẹ́ rẹ̀ lókè òkun

Oríṣun àwòrán, @Imam_Genset
O ṣeeṣe ki ọrọ ina ọba to n ṣe mọnamọna ni Naijiria maa lojutu laipẹ, lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari ya owo to le ni biliọnu mẹsan an naira sọtọ ninu aba eto iṣuna ọdun 2020 lati ra ẹrọ amunawa.
Owo naa tun wa fun rira epo ati atunṣe awọn ẹrọ amunawa kaakiri ẹka ijọba fun ọdun 2020.
Bakan naa ni ijọba apapọ tun ya miliọnu marundinlọgọrin sọtọ fun atunṣe ati rira epo si gbogbo ẹrọ amunawa to wa lolu ileeṣẹ ijọba Naijiria nilẹ okeere.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ọmọ ọdún méje ni mo bẹ̀rẹ̀ òwò nàbì nílé aṣẹ́wó tó tóbi jùlọ lágbàyéé"
- Omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù, ilé mẹ́ta wó, èèyàn mẹ́rin kú l'Eko
- Odunlade fijó bẹ́ẹ, Lizzy padà sọ́dún 2012, Toyin Abraham tọ̀ lẹ́ẹ̀mẹwàá
- Ìdí rèé tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fipá bámi lopọ̀ lọ́mọ ọdún méje lọ́gọ́ta ọdún sẹ́yìn-Eli
Ẹkunrẹrẹ gbogbo rẹ wa ninu aba eto iṣuna ọdun 2020 ti Aaarẹ Buhari gbe lọ siwaju ile aṣofin agba l'Abuja lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to lọ, ti ileeṣẹ ologun nikan yoo si lo owo to le ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu naiira lati ra epo si ẹrọ amunawa lasan.

Oríṣun àwòrán, @Imam_Genset
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu EFCC yoo na ọdunrun un miliọnu o le mẹtala lori ẹrọ amunawa, EFCC ni yoo nanwo to pọju sikeji lori ẹrọ amunawa lọdun 2020.
Awọn onimọ nipa eto ẹnawo sọ pe, biliọnu mẹsan naira tijọba ya sọtọ fun ẹrọ amunawa yii, ju owo to wọle sapo ijọba ipinlẹ mẹtadinlogun ni Naijiria lọ, fun oṣu mẹfa akọkọ lọdun 2019.
Bakan naa ni wọn sọ pe o ṣeeṣe ki o ju owo ti ijọba ya sọtọ fun ajọ eleto idibo INEC ati ajọ to n ri si ọrọ ilera, NHIS lọ ninu aba eto iṣuna ọdun 2020.
Biliọnu mẹsan an ti ijọba yoo na lori ẹrọ amunawa jẹ iyalẹnu fun ọpọ lẹyin ti ijọba ti sọ pe ina ọba ti gberu si ni Naijiria.












