Abdullahi, Ẹni ọdún 52 rí ẹ̀wọ̀n he nítorí pé ó jí fóònù méjì gbé ní Abeokuta

Computer Village

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileẹjọ Majisireti nipinlẹ Ogun ti ran arakunrin ẹni ọdun mejilelaadọta lọ si ẹwọn oṣu mẹta nitori o ji ẹrọ ilewo meji ni ilu Abẹokuta.

Lasiko ti o ba wa ni ẹwọn yii ni yoo ma ṣiṣẹ ilu ni agbegbe agọ ọlọpaa Adigbe ni ilu Abẹokuta to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun.

Arakunrin Abdullahi ti wọn ko fi adirẹsi rẹ si ita ni Adajọ ni wi pe o jẹbi ẹsun iwa ole.

Adajọ Majisreti, Dehinde Dipeolu lo ran arakunrin Abdullahi lọ si ẹwọn naa lẹyin to jẹwọ wi pe lootọ ni oun jale, to si bẹ ileẹjọ wi pe oun ko ni ṣe bẹẹ mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ ni agbẹjọrọ Lawrence Olu-Balogun ni Ọjọ Kọkandinlogun, Osu Kini ni arakunrin naa jale ni agbegbe Panseke ni Abeokuta ni ipinlẹ Ogun.

Lawrence ni Abdullahi wọ sọọbu meji ni agbegbe naa ni bi ti wọn ti n ṣiṣẹ ẹrọ kọmputa ati ileeṣẹ ti wọn ti n ran aṣọ ni agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Tolulope Adeleke Aire: Mo wòye pé àwọn ọkùnrin Nàìjíríà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ tu

Lẹyin yo wọle tan lo ba ṣe bi ẹni pe o fẹ ki wọn ba oun ṣe iṣẹ, amọ ohun ini wọn lo ko lọ.

''Abdullahi wọ sọọbu Ogundipe, to si sọ wi pe ohun fẹ ṣe I.D kaadi , amọ nigba ti Ogundipe n ba awọn onibara miran sọrọ lọwọ, lo mu foomu rẹ ti iye owo rẹ jẹ N54,000, to si yọ lọ.''

''Lẹyin naa lo lọ si sọọbu Arakunrin Olorunmade, to si sọ wi pe oun fẹ ran aṣọ, amọ o ri i wi pe ko si ẹni to kọju si oun, o si ji foonu miran nibẹ ti iye owo rẹ jẹ N42,000''

Adajọ lasiko to n ka idajọ rẹ ni wi pe iwa ole jija tako ofin ipinlẹ Ogun, iyẹn section 390 (9) ti criminal code laws ti ọdun 2006, ni ipinlẹ Ogun.

Lẹyin naa lo ni ki ọkunrin to jale naa, Abdullahi ni ko lọ sin ilu fun oṣu mẹta nipa titun ayika ṣe, ko ma gba awọn ibi to dọti ko si maa ko idọti oju popo ni Adigbe.

Àkọlé fídíò, LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...