Business investment money: Wo ọ̀nà márùn ún tí o fi lè rí owó láti fi ṣòwò lọ̀dún 2021 pẹlu ìrọ̀rùn

Oríṣun àwòrán, others
Ọ̀nà márùn ún rèé láti fi rí owó kún òwò rẹ:
Lara awọn iṣoro ti awọn oniṣowo máa n dojukọ lóde òní ni owo lati bẹrẹ tabi fi kun okowo wọn.
Pupọ awọn tó máa n bẹrẹ owo ni wọn máa n kogbawọle nítorí kò sí owo lati ṣ'owo náà bo ṣe tọ àti bó ṣe yẹ.
Gbogbo èèyàn ló mọ pé owo kii so lori igi, idi ree ti ileeṣẹ iroyin BBC Yorùbá ṣe ṣe akojọpọ awọn ọna marun un ti èèyàn fi le ri owo lati fi ṣ'owo.
- Òfin kónílé-ó-gbélé gbòde nílùú Igangan lórí ẹ̀rù pé Fulani le k'ógun wá lẹ́yìn àbẹ̀wò Igboho
- Wo àwọn sinimá mẹ́wàá tó gbé sinimá Yorùbá sáyé
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ṣé lọ́ọ̀tọ̀ ní àkúdááyà wà? ẹ̀ wo ìrírí àwọn tó rí ènìyàn wọn tó kú láàyè
- Ẹ yé ṣí ìhòhò ara yín síta lórí ayélujára torí ‘Silhouette Challenge’ - Adeboye
1) Owo ara ẹni:
Nina owo ara ẹni lati fi s'owo jẹ ohun tó ni ere pupọ, nitori irufẹ ẹni bẹẹ ko ni ko sinu oko gbèsè.
Eyii jẹ ohun tó maa n ṣoro diẹ lọpọ ìgbà, pàápàá ti èèyàn bá ṣẹṣẹ bẹrẹ owo bẹẹ, ṣugbọn adùn lo máa n gbẹyin ewúro.
2) Ẹbi àti ọrẹ:
Ti owo tí o ni ko ba to nnkan, ko burú ju ti o ba lọ bá àwọn ẹbí àti ọrẹ rẹ fún owo lati fi ṣowo.
Bó tilẹ jẹ pé o ṣoro fún ọpọ èèyàn láti ran ẹlòmíràn lọwọ to ba ti di ọrọ owo, ṣugbọn, awọn miran le dide iranlọwọ ti owo náà bá jẹ èyí tó ní ọjọ iwájú tó dára.
Ki o to ya owo lọwọ ẹbi tàbí ọrẹ rẹ, o gbọdọ ti ni eto bi òwò náà yóò ṣe lọ lọwọ, bákan náà ni o gbọdọ ti ni eto bi o ṣe máa san owó náà padà nítorí ọjọ miran.
3) Awọn olójú aanu lawujọ:
Awọn èèyàn kan wà to jẹ pe ohun ti wọn máa n fi owo wọn ṣe ni lati fi da awọn ẹlomiran to ni afojusun rere lokowo, niwọn igba ti oniṣowo náà bá ti ni afojusun rere.
Pupọ ninu awọn ileeṣẹ nla to ti di gbajumọ lóde òní bíi Google, Yahoo ati Paystack ló jẹ pé àwọn olójú anu lo dá sí ọrọ wọn nigba ti wọn ṣẹṣẹ n dagba bọ.
Yatọ sí pé wọn gbé owo kalẹ, awọn olójú anu miran tun máa n ṣe itọni fún àwọn oníṣòwò tọ ṣẹṣẹ n bọ.
4) Owo àdájọ:
Yatọ sí pé ọpọ èèyàn tí n ṣe káràkátà lórí ayélujára, awọn kan náà ti n ṣe ikowojọ fún owo lórí ayélujára tí wọn a sì pé ọpọ ero láti dá owó jọ fún owo ti wọn fẹ ṣe.
Bi wọn ṣe máa n ṣe ni pé ẹni tó bá fẹ ṣe owo náà yóò fi orúkọ silẹ lórí ìkànnì ayélujára.
Iru ẹni naa yóò sì sọ iye owó tó n gbiyanju láti kó jọ, awọn olójú anu yóò si máa dá owó náà lai ni ìrètí pé wọn fẹ gba ohunkohun pada.
Nipasẹ èyí, oníṣòwò le rí owo gba lọwọ àwọn oninu ire káàkiri àgbáyé.
5) Owó yiyá:
Pupọ èèyàn ni ko gbagbọ nínú owo yiya, ti ẹru sí máa n ba awọn miran, ṣugbọn owoya jẹ ọnà kan gbòógì ti èèyàn fi lè rí owo lati fi ṣowo.
Ki àwọn ileeṣẹ tabi ilẹ ifowopamọ kan tó lè ya eeyan lowo, irufẹ ẹni bẹẹ ni lati ṣe afihan pe owo ti oun n ṣe ti n pa owo wọlé.
Lakotan, ẹnikẹni tó bá fẹ ṣòwò ni láti mọ irufẹ owo tó fẹ ṣe, ati ọna to rọrùn fún ju lati ri owo ṣe owo náà.
- Wo bí o ṣe lè di ọmọ onílùú ní Dubai pẹ̀lú òfin tuntun orílẹ́èdè U.A.E.
- Ẹ yé ṣí ìhòhò ara yín síta lórí ayélujára torí ‘Silhouette Challenge’ - Adeboye
- Èèyàn mẹ́tàdínlógún(17) jọ́ná ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì lópòpóónà Bode-Saadu sí Jebba
- Òfin kónílé-ó-gbélé gbòde nílùú Igangan lórí ẹ̀rù pé Fulani le k'ógun wá lẹ́yìn àbẹ̀wò Igboho
















