Man City vs Man United: Manchester City po ẹ̀kọ ìbànújẹ́ fún Manchester United pẹ̀lú 4-1

Awọn agbabọọlu Man city n dunu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ija agba meji laarin ikọ agbabọọlu Manchester city ati manchester United ti yanju ọrọ si akata Manchester City pẹlu bi Debryne atawọn akẹgbẹ rẹ ṣe na manchester United bi ẹni na bara.

Goolu mẹta si ẹyọkan ni City fi jẹwọ 'awa la nilu' fun Manchester United ni ifẹsẹwọnsẹ 'Manchester derby" naa.

Kevin De Bruyne lo kọkọ ṣide fun Manchester city nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mejila ki Jandon Sancho to da a pada bi owo baba ijẹbu nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mejilelogun.

Debruyne tun fi ọkan le nigba ti bọọlunaa wọ iṣẹju kejilelogoji.

Riyad Mahrez tun fi goolu kan sii nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejidinlaadọrin ko to de e lade nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkanlelaadọrun.

Ifẹsẹwọnsẹ Manchester City ati Manchester United

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn iroyin fidi rẹ mulẹ pe pẹlu ara ti De Bruyne da ninu ifẹsẹwọnsẹ 'Manchester derby' tọtẹ yii, o ti di igba mejidiinlaadọrun ti Debruyne ti ni ipa ati ipin ninu goolu ti wọn gba wọle ninu ọgọrun ifẹsẹwọnsẹ to gba ni ibuba ẹgbẹ agbabọọlu rẹ lasiko to wa pẹlu Chelsea ati isinyi to wa pẹlu manchester city.

Igba kejilelogun ree ti Manchester United ati Manchester city yoo maa koju ara wọn ni idije premier league niyi, amọṣa man United lo n bori lọpọ igba julọ.

Christiano Ronaldo ko lee kopa ni ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bi iroyin ṣe jade pe o ti ko COVID-19 pẹlu