Ukraine crisis: FIFA pàṣẹ pé Russia kò gbọdọ̀ díje pẹ̀lú àṣíá orílẹ̀èdè rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @FIFA
FIFA pàṣẹ pé Russia kò gbọdọ̀ díje pẹ̀lú àṣíá orílẹ̀èdè rẹ̀
Ajọ ere bọọlu lagbaye, FIFA ti paṣẹ fun Russia pe orilẹede miran ni yoo ti maa gba awọn ifẹsewọnsẹ rẹ yoku.
Koda, wọ́n ni ko si gbọdọ lo orukọ Russia gẹgẹ bi orilẹede bikoṣe orukọ ajọ agbabọlu orilẹede naa, Football Union of Russia.
Igbesẹ ti FIFA gbe yi n waye pẹlu bi Russia ṣe ṣigun wọ Ukraine lọjọ diẹ sẹyin.
Bakan naa lajọ FIFA tun paṣẹ oe wọn ko gbọdọ kọ orin orilẹde Russia nibi ifẹsẹwọnsẹ rẹ kankan; bẹẹ ni asia rẹ ko gbọdọ si nibẹ.
Kini awọn orile-ede mii ti se?
Ọpọ awọn orilẹede bii England, Wales, Poland, Czeck Republic ati Sweden lo ti sọ pe awọn ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan to ba nii ṣe pẹlu Russia.
Russia yoo kopa ni ifẹsewọnsẹ tani yoo lọ idije agbaye pẹlu awọn orilẹede bii Poland ki o to koju eyikeyi ninu Sweden tabi Czech Republic loṣu kẹta ọdun yii.
Ajọ FIFA ni ijiroro yoo ṣi waye pẹlu awọn ajọ ere idaraya miran lori boya ki wọn le Russia kuro lawọn idije wọn gbogbo.
FIFA ni ajọ naa ko fara mọ iwa ipa, bi o ti wulẹ ko mọ , bẹẹ lo ba awon eeyan Ukraine kẹdun lori ikọlu naa.
Ipe fun fifofin de Russia lajọ ere idaraya Olympics ati Paralympics.
Lọjọ Aiku, ẹgbẹ kan to jẹ tawọn elere idaraya lorilẹde Ukraine pe fun fifofin de awọn elere idaraya Russia ati Belarus lati maṣe kopa lawọn idije ere idaraya gbogbo.
Ẹgbẹ naa kọwe si ajọ ere idaraya Olympics, IOC ati ajọ ere idaraya Paralympics IPC lati fofin de Russia ati Belarus lesekese.
Wọn ni igbesẹ naa ṣe pataki pẹlu bi Russia ṣe ṣigun wọ Ukraine.
- Kini Wòlíì rí tó fí yìnbọn lú arábìnrin ẹní ọdún 18 tó sá wọ ilé ìjọsìn rẹ́?
- Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìkọlù Russia sí Ukraine àti ìgbésẹ̀ rẹ̀ lórí àwọn ọmọ Naijiria tó wà níbẹ̀
- Ẹ gbàgbé pé mo lọ gba ìtọ́jú ní London, mo ní ọpọlọ pípé láti tukọ̀ Naijiria - Tinubu
- Ọmọ Nàìjíríà tó há sí Ukraine kò nílò físà láti wọ Romania àti Poland- Ìjọba Nàìjírí
Awọn eeyan lagbo ere idaraya ṣi n fẹhonu han
Ajọ ere idaraya Judo ti yọ Aarẹ Vladimir Putin kuro gẹgẹ bi baba isalẹ ajọ naa.
Awọn ajọ ẹṣẹ kikan bii IBF, WBC, WBA ati WBO ni wọn ti sọ oe awọn ko ni fọwọ si idije ẹṣẹ Nkan ti yoo ba waye ni Russia.
Lagbo ere idaraya to ku n ko?
Bakan naa ni gbajumọ elere Tennis ọmọ Ukraine kan, Elina Svitolina ti kede pe oun yoo ko owo ere idaraya ti oun ba pa ranṣẹ sawọn ologun ilẹ naa atawọn to n moju to ipenija ilu lasiko ogun naa.
Bẹẹ ni idije ife ẹyẹ agbaye ere idaraya Fencing to n lọ lọwọ ni Cairo, awọn oludije kati Ukraine kọ lati koju awọn ti Russia ni ifẹsẹwọnsẹ ti yẹ ko waye laarin awọn mejeeji.
Kini o n sele ninu idije to ku?
Bakan naa ni Baba olowo to ni ẹgbẹ agbabọlu Chelsea, Roman Abramovich ti ọpọ woye pe o sunmọ Aarẹ Putin pẹkipẹki pẹlu ti fa akoso Chelsea le awọn ewyan miran lowo ninu igbesẹ tawọn eeyan kan woye oe ko ṣai nii ṣe pẹlu ohun to n waye laarin Russia ati Ukraine.
Ẹwẹ, Ajọ ere idaraya iwẹ wiwẹ lagbaye, FINA pẹlu ni awọn ti wọgile idije iwẹ wiwẹ awọn ojẹ wẹwẹ to yẹ ko waye nilu Kazan loṣu kẹjọ ọdun yii.















