Bola Tinubu fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìlera rẹ̀

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @Mr_JAGs

Oludije sipo Aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ oṣleu APC, Bola Tinubu ti sọ pe ọlọpọlọ pipe ni oun, oun si ni awọn amuyẹ to tọ lati tukọ Naijriia.

Tinubu lo ṣo ọrọ naa lasiko to ṣabẹwo si aafin Ataoja niluu Osogbo, nibi to ti rọ ori ade naa lati ṣatilẹyin fun oun lọna ati di Aarẹ lọdun 2023.

O ni oun ko ni ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ ti wọn ba le gbaruku ti oun de ipo naa.

Eekan ẹgbẹ APC naa sọ pe "Akoko ti to... Naijiria nilo ireti fun ilọsiwaju ati aluyọ."

"Mo ti fa ara mi kalẹ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria, mo si ti fi erongba mi han fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe mo fẹ ti ẹsẹ bọ bata ti yoo bọ silẹ."

"Mo ti sọ fun Aarẹ pe mo fẹ sin orilẹ-ede mi... mo si nilo atilẹyin ati adura ẹyin naa."

Tinubu sọ siwaju si pe awọn ọmọ Naijiria gbọdọ ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ lai fi ti ẹsin tabi ẹya ṣe.

Àkọlé fídíò, 'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ẹsin tabi ẹya wa le yatọ, amọ ọmọ iya kan naa ni gbogbo wa.

Tinubu fesi si ọrọ awọn eeyan nipa ilera rẹ

Oludije naa ni ọpọ awọn eeyan lo ti n sọ oniruru ọrọ nipa ilera oun, paapaa lasiko to lọ silu London fun itọju orokun to n dun un.

Tinubu ni ẹsẹ to n dun oun ko ni ki oun ma du ipo Aarẹ niwọn igba ti iṣẹ Aarẹ kii ṣe iṣẹ agbẹkanga tabi iṣẹ agbẹboji, nitori naa ọpọlọ ni oun nilo, kii ṣe okun.

O ni "Iṣẹ ti mo fẹ ṣe kiiṣe iṣẹ awọn to n mọ biriki tabi gbẹ iboji, mo kawe nipa eto iṣoro."

"Iṣẹ ọlọpọlọ pipe ni mo fẹ ṣe, ọpọlọ mi si pe daadaa nitori naa, n o ṣe iṣẹ naa laṣeyọri."

Nigba to n fesi, Ọba Jimoh Olanipekun ni Tinubu koju oṣuwọn lati ṣe iṣẹ Aarẹ.

Lẹyin naa lo gbadura pe ki Eledua jẹ ko ri fun bo ṣe n gbero.

Àkọlé fídíò, Diabetes Ulcer