Uromi Bank Robbery: Ohun tí a mọ̀ nípa ₦34.5m àti ọkọ̀ táwọn adigunjalè patì sínú igbó ní Ubiaja rèé

Aworan ọkọ ato owo ti ọlọpaa ri gba

Oríṣun àwòrán, Naija Blog

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo sọ pe awọn ti ri ọkọ pẹlu owo ti awọn adigunjale kan ji gbe ni Uromi ni ipinlẹ Edo gba.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa ipinlẹ Edo, Bello Kotings fi sita lọjọ Ẹti lo ti ṣalaye ọrọ yi.

O ni awọn ri owo naa ninu awọn ọkọ tawọn adigunjale yi pati si inu igbo lagbegbe Ubiaja ni ijọba ibilẹ Guusu ila oorun Esan.

Atẹjade yi tẹsiwaju pe kete ti awọn gburo pe wọn pa owo yi ati ọkọ ti sinu igbo lawọn tara lọ sibẹ pẹlu awọn fijilanti adugbo ati oriade ilu Ubiaja.

Iroyin yi jẹ nkan to dun mọ awọn araalu ninu paapa pe wọn tiẹ ri owo tawọn adigunjale yi ji gbe sugbọn alaye ohun to mu awọn ole yi fi owo kalẹ ko ye wa si.

Ki la mọ nipa idigunjale yi?

Nirọlẹ Ọjọbọ ni iroyin gbode pe awọn adigunjale kan ṣe ikọlu sawọn ile ifowopamọ mẹrin kan ni ilu Uromi ni ipinlẹ Edo.

Ninu ikọlu yi gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ti ṣe sọ fun BBC,araalu marun un ati ọlọpaa meji lo padanu ẹmi wọn ti awọn adigunjale yi si gbe owo salọ.

Ni nkan bi ago marun un irọle ni alukoro ọlọpaa sọ pe iṣẹlẹ naa waye.

2px presentational grey line

Kaakiri oju opo ayelujara ni awọn eeyan ti ṣe alabapin fọnran fidio to ṣe afihan bawọn adigunjale yi ti ṣe n yan fanda fanda loju titi ti wọn si n ko apo owo sinu ọkọ.

Iṣẹlẹ yi jẹ nkan to fọwọ kan araalu lẹmi koda igbakeji Gomina Godwin Obaseki,Comrade Philip Shaibu,ṣe abẹwo si awọn ile ifowopamọ to farakasa iṣẹl yi ati awọn to n gba itọju nile iwosan.

Àkọlé fídíò, Diabetes Ulcer

Ki wa lo mu ki awọn adigunjale yi fi owo ati ọkọ silẹ salọ?

Ariwo awọn ọdọ ilu Ubiaja nibi ti wọn ti ri owo, ọkọ ati alupupu ni awọn eeyan n mu bẹnu loju opo ayelujara.

Iroyin to twa lọwọ ṣugbọn ti a ko ribi fidi rẹ mulẹ ni pe awọn ọdọ ilu Ubiaja da awọn ole wọn yi lọna lẹyin ti wọn ṣọṣẹ tan ni Uromi.

Ko si ẹni to sọ pato boya wn doju ija kọ wọn ni ṣugbọn iroyin naa sọ pe igbesẹ awọn ọdọ yi lo mu ki awọn ole naa pa ọkọ wọn ti ti wọn si salọ.

Aworan ikọlu si ile ifowopamọ

Oríṣun àwòrán, Esan People Blog

Ninu ẹda iroyin miran taa tun gbọ ni pe ọkọ tawọn ole naa gbe taku sọna lo mu ki wọn pati sinu igbo.

Ati alaye alakọkọ ati ẹlẹẹkeji ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade ti wọn fi ṣalaye pe awọn ri owo ati ọkọ gba pada ko fidi nkankan mulẹ ninu wọn.

Yala ohun ti ọlọpaa sọ ni pe awọn gburo pe awọn adigunjale yi pa ọkọ ti sinu igbo tawọn si tara lọ sibẹ pẹlu fijilante ati oriade ilu Ubiaja

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Akọkọ idigunjale kọ nii lẹnu ọjọ mẹta yi ni Naijiria.

Aisi aabo to peye jẹ nkan to n kan ijọba ati awọn araalu lominu ni Naijiria.

Laipẹ yi ni ilu Ibdan ni iṣẹlẹ idigunjale si ile ọkọ agboworin ile ifowopamọ ti awọn alaburu yi si ṣeku pa awọn ọlọpaa mẹtaa ati awọn eeyan mẹrin mii.

Awọn adigunjale yi dojuija kọ awọn ọlọpaa toi tẹle ọkọ agboworin naa lagbegbeIdi Ape loṣu keji ọdun yi.

Aworan ọkọ tawọn adigunjale da ibọn bo ni Ibadan

Oríṣun àwòrán, TVC News

Awọn adigunjale yi la gbọ pe wọn to mẹwaa ti wọn si dira wa ṣe iṣẹ lọjọ taa n wi yi.

Kọmiṣana ọlọpaa Ngozi Onadeko sọ pe awọn ọlọpaa naa pa adigunjale kan ṣugbọn awọn iyoku rẹ gbe oku rẹ salọ.

Afihan aworan ile ifowopamọ tawọn adigunjale kọlu ni ipinlẹ Osun

Kini o ti koko sele télẹ̀ Ipinlẹ Osun?

Ni ọdun to kọja lawọn alaburu kọlu banki ni ilu Apomu ati Ikire ni ipinlẹ Osun.

Ọjọ keji oṣu Kẹfa ọdun 2021 niiṣẹlẹ yi waye.

Ati ile ifowopamọ ati agọ ọlọpaa ni wọn kọlu ti wọn si dabọn bole lati fi dẹru ba araalu.

Titi di ba ṣe n ko iroyin yi jọ, a ko ti gbọ pe awọn ọlọpaa ri awọn adigunjale yi mu.