Police, road safety Marshal killed in Ekiti: Bí Ọlọ́pàá àti ọ́ọ́físà àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó se kú níbi idigunjale Banki Aramoko Ekiti

Ipaniyan

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn adigunjale kọlu ilé ifowopamo kan ni ilu Aramoko, Ìpínlẹ̀ Ekiti ni ọjọ Aje èyí tó ti mú èmi èèyàn méjì lọ ti awọn míì sì fara pa.

Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o ṣẹlẹ ni ìrọlẹ ọjọ Aje. Iroyin ni awọn adigunjale kọlu ile ifowopamọ Wema to wa ni aarin gbungbun ilu naa ati agọ Ọlọpaa ilu ọhun lẹẹkanṣoṣo.

Ṣe ni awọn ara adugbo n sa asala fun ẹmi ara wọn lasiko iṣẹlẹ naa eyi to ni ọpọlọpọ iro ibọn ninu ati awọn nkan ti wọn gbagbọ pe abugbamu niwọn.

Àkọlé fídíò, Ilé tẹ́ẹ rò pé ìjọba Eko fún wa, wọ́n rẹ́ǹtì rẹ̀ ni, a kò tíì rí N1Miliọ̀nù kankan di àsìkò yìí - Iya Jumoke

Lẹyin iṣẹlẹ naa to to wakati kan gbako, awọn to ṣoju wọn koro ni ṣe ni awọn adigunjale ọhun na papa bora si opopona Aramoko si Erinjiyan.

Nigba ti akọroyin wa ba Ọlọpaa sọrọ, alukoro wọn ni ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu sọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

O ni ọlọpaa naa ṣẹṣẹ pari iṣẹ rẹ ni lọjọ naa ti wọn si pa oun ati oṣiṣẹ àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó kan.Abutu sọ pe iṣẹlẹ idgunjale ni ati pe ọlpaa ti gba ọkọ meji ti awọn lo fun iṣẹ aburu yii wọn si ni ko si owo ti wọn ri ji lọ ni banki ọhun.

A gbọ pe wọn ti gbe awọn to farapa nibi iṣẹlẹ ọhun lọ si ile iwosan mii lẹyi ti wọn kọkọ gbe wọn lọ ile iwosan gbogbo-niṣe ti ijọba nigba ti wọn si ti gbe oku awọn to baa lọ si ile igbokupamọ si.