Timothy Adegoke Murder: Wo ìlérí tí Sẹ́nétọ̀ Kola Balogun ṣe fún ìdílé olóògbé

Oríṣun àwòrán, Others
Sẹnetọ Kola Balogun ti ṣeleri pe oun yoo ri daju pe awọn mọlẹbi Timothy Adegoke to ku sile itura Hilton ni Ile Ife ri idajọ ododo gba.
Kola Balogun, to n sọju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Oyo nile igibimọ aṣofin agba lo ṣe ileri naa lasiko to bẹ ẹbi oloogbe naa wo ni Eruwa, nipinlẹ Oyo.
Nibi abẹwo naa lo ti ṣeleri lati gbe bukata owo ile ẹkọ awọn ọmọ oloogbe to jẹ ibeji ti wọn n kẹkọọ niluu Abuja.
- Jumoke Oyeleke: Iya Jumoke kọ̀ láti lọ ilé tí ìjọba rẹ́ǹtì, ó ní òun ò lè padà sí ẹ̀sẹ̀ àárọ̀ lẹ́yìn ilé mè-rẹ́ẹ̀ǹtì
- Wo ọ̀nà táwọn olólúfẹ́ Baba Suwe ní London àti Manchester fẹ́ gbà ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fun
- BBC Africa Eye: Ìwádìí tú àṣírí bí ààrẹ orílẹ̀-èdè DR Congo ṣé lú owó aráàlú ní pónpó
- Timothy Adegoke: Kò pẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ ẹ̀jọ́ lórí ikú àbúrò mi ni Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì rán lawyer kó gbé owó wá - Ẹ̀gbọ́n Timothy
Nigba to n ba awọn mọlẹbi oloogbe naa sọrọ, Balogun sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Adegoke ko ni lọ lai foju wina ofin.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ sẹnetọ ọhun, Dapo Falade fi sọwọ si BBC Yoruba lẹyin abẹwo naa, o ni o jẹ ohun ibanujẹ pe awọn kọlọrọsi kan le gba ẹmi Adegoke, to jẹ ọdọ langba to si n gbiyanju lati kawe ati lati ṣiṣẹ fun ọjọ ọla rẹ ati fun awọn ọmọ rẹ.
Ile itura Hilton to wa ni Ile Ife ni wọn ti gbẹmi Timothy Adegoke lasiko to wọ sibẹ ni imurasilẹ idanwo rẹ ti yoo waye ni ọjọ keji ni fasiti Obafemi Awolowo.
Bo tilẹ jẹ pe Kola Balogun ṣeleri lati bẹrẹ si n san owo ile ẹkọ awọn ibeji loogbe, o ni ki ẹbi naa fa ọrọ naa le Ọlọrun lọwọ.
O ni "Ọlọrun yoo ṣe idajọ… Gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Adegoke ko ni lọ lai jiya."
Ẹwẹ, iyawo oloogbe naa ti sọ fun BBC ṣaaju pe ọna atijẹ-atimu ni ọkọ oun n wa kiri ko to ṣagbako iku nile itura to wọ si iku ojiji to de ba.
O si ke si gbogbo ọmọ Naijiria lati gbaruku ti oun ki iku ọkọ ma baa lọ lasan.
Ko din ni eeyan meje to ti wa ni galo ọlọpaa bayii lori iku oloogbe ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti iṣẹlẹ naa ti waye, Yemisi Opalola naa ba BBC Yoruba sọrọ pe awọn ṣi n ṣe iwadii lọwọ, awọn ko si ni fi ohunkohun pamọ lori abajade iwadii awọn.
Ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni Timothy Adegoke ki wọn to dẹmi rẹ legbodo.
Sẹ́nátọ̀ Kola Balogun ní àwọn ènìyàn ibi tó pa Timothy kò ní lọ láì jẹ́jọ́ òfin
Sẹnatọ Kola Balogun ti ṣe ileri lati ri pe idile Timothy Oludare Adegoke tí wọn pa ni ipakupa ni Ile Ife ni ipinlẹ Osun ni ibẹrẹ osu yii yoo gba idajọ ododo, ti gbogbo àwọn tí ni ọwọ ninu iku rẹ ni yoo fi oju wina ofin.
Sẹnatọ naa to n soju ẹkun Oyo South lo ṣe ileri naa lasiko to lọ ki o ẹbi naa ku ọrọ eeyan ni ilu Eruwa nijoba ìbílẹ̀ Ibarapa East lọ́jọ́ Aje
O kede eyi ọrọ niwaju ẹbi oloogbe naa pe oun yoo mojuto eto ẹkọ awọn ibeji ẹni ọdun meje tí wọn wa ni ipele kẹta ẹkọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ n'ilu Abuja
Timothy, ẹni ọdun mẹ́tàdínlógójì to lọ kawe lati gba oye MBA ni ile ẹkọ OAU ni iroyin sọ pe wọn da ẹmi rẹ legbodo nile itura Hilton ti o gba lati gbaradi fun idanwo to fẹ ṣe.
Lasiko ti n ba awọn obi Timothy tí wọn ti darugbo iyawo oloogbe ati awon ọmọ rẹ mẹtẹẹta, Balogun fi ọkan wọn balẹ pe ẹni tí o da ẹ̀mí Timothy legbodo ko ni bọ lọwọ ofin.

Oríṣun àwòrán, Others
O ni o ṣeni laanu pe iru iwa buruku naa le koba ọdọ ọkùnrin to n ṣíṣe rẹ deede tó sì ń gbiyanju lati ni ọjọ ọla ti o dara fun ara rẹ àti ẹbi rẹ.
Balogun rọ ẹbi naa lati fi gbogbo rẹ si ọwọ Ọlọ́run, kí Ọlọ́run si ṣe idajọ rẹ, sugbọn ẹni ti o hu iru iwa ibajẹ yii ko ni lọ lai jẹya.














