Oyebade Adebimpe: Kò ṣeéṣe kí n lóyún, kí n sì gbe pamọ́ lọ́jọ́ orí mi

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajumọ òṣèré tiata Yorùbá, Oyebade Adebimpe ti sọrọ lori iroyin to n lọ ni igboro pe o ti loyun fun akẹgbẹ rẹ, Lateef Adedimeji.
Ọrọ yìí ló n jade lẹyin ti awọn oṣere mejeji ni lootọ ni wọn n mura igbeyawo, eyii tí yóò waye ninu oṣu Kejila, ọdún yìí.
Ṣaaju ni awọn eeyan ti kọkọ n sọ pé Adebimpe ti loyun fun Lateef, eyii to ṣokunfa igbeyawo ti wọn n mura rẹ lọwọ.
- Wo ọ̀nà táwọn olólúfẹ́ Baba Suwe ní London àti Manchester fẹ́ gbà ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fun
- Ọ̀sere tíátà kan rí ẹ̀bùn owó ₦8m gbà
- Mí ò polongo ìdupo ààrẹ ọdún 2023 fún Tinubu-Foluke Daramola
- Mo ti bẹ̀rẹ̀ ètò lórí ayélujára nípa Baba Suwe, tí orúkọ̀ rẹ̀ kò fi ní parun - Adesola Omidina
- Baba Suwe ti kú tipẹ́ ṣaájú kí gbogbo èèyàn tó mọ̀ - Àbúrò olóògbé
- Ìrìn-àjò Baba Suwe pẹ̀lú àjọ NDLEA lórí bó ṣe ''yàgbẹ́ tì'' ní àtìmọ́lé
- Woli Agba Ayo Ajewole: Mo bọ́ sínú ọkọ̀, mo kéé gidi gan mo sì nu ojú nù lọ ṣe eré lórí ìtàgé
- Wo àwọn gbajúmọ̀ aláwàdà Yorùbá méje tó ti kú saájú Baba Suwe
Wayii o, Adebimpe ti fi fidio kan lede loju opo Instagram rẹ, ninu eyi ti apẹrẹ oyun ko hàn lara rẹ.
Ṣugbọn awọn kan lára àwọn ololufẹ rẹ wà n bere lọwọ rẹ labẹ fídíò náà nipa oyun ti awọn eeyan sọ pé ọ wa ninu rẹ.
Ṣugbọn nígbà tí yóò fesi, o ni ìbùkún Oluwa ni oyun, oun kò sí ní fi ọwọ bo mọlẹ ti akoko oun ba pe lati ni oyún.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Adebimpe ni "Ohun tó ba wu ẹlẹnu lo lè fi ẹnu rẹ sọ, mi o kere ju lati lóyún tàbí lati bi ọmọ."
"Ti mo ba dẹ loyun mi ọ ni gbe oyun naa pamọ nítorí ibukun Olúwa ni ọmọ bíbí jẹ."
- Jumoke Oyeleke: Iya Jumoke kọ̀ láti lọ ilé tí ìjọba rẹ́ǹtì, ó ní òun ò lè padà sí ẹ̀sẹ̀ àárọ̀ lẹ́yìn ilé mè-rẹ́ẹ̀ǹtì
- Wọ́n yọ ẹ̀yà ara màmá wa tí wọn pa ní ṣọ́ọ́ṣì Deeper lọ - Ẹbí pariwo
- ''Àwọn ènìyàn ibi tó pa Timothy kò ní lọ láì jẹ́jọ́ òfin''
- 'Láti Dec 1, iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́rin péré láàrín ọ̀ṣẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa ṣe báyìí'
- ''Láí! ó dá wa lójú pé kò sí ohun tó jọ ẹ̀dà covid-19 tuntun Omicron Variant ní Naijiria"
- BBC Africa Eye: Ìwádìí tú àṣírí bí ààrẹ orílẹ̀-èdè DR Congo ṣé lú owó aráàlú ní pónpó
- Timothy Adegoke: Kò pẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ ẹ̀jọ́ lórí ikú àbúrò mi ni Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì rán lawyer kó gbé owó wá - Ẹ̀gbọ́n Timothy
Ẹnu ọjọ mẹta yii ni Adebimpe ati Adedimeji sọ ni gbangba pe àwọn fẹ ṣe ìgbéyàwó loṣu Kejìlá.
Ẹwẹ, ṣáájú ni awọn méjèjì ti kọkọ sẹ pé àwọn wọn kìí ṣe ololufẹ.












