El-Rufai: Ọjọ́ mẹ́rin láàárín ọ̀ṣẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa lọ sí ibi iṣẹ́ báyìí'

Workers dey protest for Kaduna

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede pe ọjọ mẹrin laarin ọṣẹ ni awọn oṣiṣẹ yoo maa lọ si ibi iṣẹ bẹrẹ lati Ọjọ Kini, Osu Kejila, ọdun 2021.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ni igbesẹ yii yoo mu irọrun ba awọn oṣiṣẹ lati ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.

Bakan naa ni Gomina naa fikun un pe eyi yoo ran awọn oṣiṣẹ naa lọwọ lati le faramọ mọlẹbi wọn ju ti tẹlẹ lọ nitori wọn yoo ri aye lati lo pẹlu wọn ninu ile.

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

Ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun gomina El-Rufai, Muyiwa Adekeye fi lede ni Osu Kejila ni erọngba ijọba yii yoo hggberaso.

O ni lati Osu Kẹjila ni awọn oṣiṣẹ ijọba yoo bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lati aago mẹjọ owuro titi di aago marun un irọlẹ ni Ọjọ Aje si Ọjọ Ẹti.

Amọ ni Ọjọ Ẹti, gbogbo oṣiṣẹ yatọ si awọn to n ṣiṣẹ ni awọn ileewe ati ileewosan ni yoo ṣi'sẹ lati ile.

Governor El-Rufai

Oríṣun àwòrán, Kaduna state govt

Ijọba ipinlẹ Kaduna fikun un pe bi awọn oṣiṣẹ yoo ṣe ma a ṣiṣẹ ni yii titi di igba ti awọn yoo ṣe atuntọ iye ọjọ ti awọn oṣiṣẹ yoo fi ṣiṣẹ naa, eleyii ti yoo jẹ ọjọ mẹrin.

''Igbesẹ ijọba yii jẹ ọkan lara awọn ẹkọ ti ijọba kọ lara ajakalẹ arun Covid-19, eleyii to mu ki ajakalẹ arun naa ma ni ipa buburu nibẹ.''

''Bakan naa ni asiko ajakalẹ arun naa fihan pe awọn oṣiṣẹ gbọdọ wa ọna tuntun miran lati ṣe iṣẹ wọn ki wọn ba le ṣe ni aṣeyọri.''

Gomina ipinlẹ Kaduna ni ọna tuntun yii yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ kunjuwọn nipa lilo ọna igbalode lati ṣe iṣẹ wọn.