Jos Prison Break: Gómìnà Plateau ti sọ̀rọ̀ lórí àwọn agbébọn tó kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n Jos

Oríṣun àwòrán, plsgdoppa
Ijọba ipinlẹ Plateau ti sọrọ nipa bi awọn agbebọn kan se kọlu ọgba ẹwọn to wa ni olu ilu naa Jos.
Gẹgẹ bi wọn ti ṣe sọ, ikọlu yii jẹ iyalẹnu fun wọn nitori pe ọgba ẹwọn naa jẹ ibi ti eto aabo ti gbopọn, to si tun wa lẹgbẹ agọ ọlọpaa.
Yatọ si eleyi, wọn ni ibi ti ẹwọn naa wa ko jina pupọ si ileeṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati ile ẹjọ giga ni Jos,
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni àwọn tó ni ọkọ̀ òfúrufú tí a gbẹ́sẹ̀lé gbà kó wọn wọ Naijiria – Iléeṣẹ́ Custom
- Ọ̀sere tíátà kan rí ẹ̀bùn owó ₦8m gbà
- Àwọn àjòjì ṣá obìnrin tó ń lọ gbálẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Deeper Life pa, ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ara rẹ̀
- Abiyamọ, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn kan bá ìbúgbàmù ọkọ́ aképo lọ́ ní Lafenwa
- Wo ọ̀ná tí àwọn ọkùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù lásìkò ìbálòpọ̀
Kọmisana naa ko sọ bọya eeyan kankan fara pa tabi ku ninu ikọlu naa .
Bẹẹ ko sọ boya awọn agbebọn ọhun ribi tu awọn ẹlẹwọn silẹ kawọn agbofinro to koju wọn.
O ni awọn si n ṣe akojọpọ iroyin nipa iṣẹlẹ naa amọ awọn agbofinro ti bori awọn agbebọn naa.

Ọ̀pọ̀ Agbebon tó kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n Jos há síbẹ̀ láì le jáde

Oríṣun àwòrán, Jos Prison
Ileesẹ to n se amojuto awọn ọgba ẹwọn ni Naijiria, NCS, ti kede pe awọn agbebọn kan ti kọlu ọgba ẹwọn to wa nilu Jos, nipinlẹ Plateau.
Amọ ileesẹ NCS tun salaye pe ode ko dara fun awọn agbebọn naa nitori awọn osisẹ ọgba ẹwọn naa ba wọn fija pẹẹta, ti wọn si kọju ibọn si ara wọn.
Wọn ni lẹyin o rẹyin, o nira fun awọn agbebọn naa lati jade kuro ninu ọgba ẹwọn naa, ti wọn si ha sinu ibẹ.
Agbẹnusọ fun ileesẹ NCS, Francis Enobore sọ ninu atẹjade to fisita lẹyin isẹlẹ naa pe awọn agbebọn naa, ti wọn pọ pupọ, lo ko ọpọ ohun ija oloro wa kọlu ọgba ẹwọn Jos.
O ni deedee aago marun kọja ogun isẹju ni awọn agbebọn naa gunlẹ si ọgba ẹwọn naa, ti wọn si doju ibọn kọ awọn osisẹ ọgba ẹwọn naa.
"Bi o tilẹ jẹ pe wọn ri aaye wọnu ọgba ẹwọn naa, amọ wọn ha sibẹ nigba ti awọn agbofinro kun awọn osisẹ ọgba ẹwọn lọwọ lati koju wọn.
Awọn agbofinro yii si lo yi awọn ogiri ọgba ẹwọn naa ka, ti ko si si ọna fun awọn agbebọn naa lati ri aaye jade kuro nibẹ.
A ti gba akoso ọgba ẹwọn naa pada nitori awọn agbofinro ti tẹ ori awọn agbebọn naa ba, laipẹ si ni a kede ibi ti nnkan de duro nibẹ."
Bẹẹ ba gbagbe, awọn agbebọn naa ya bo ọgba ẹwọn Jos yii ni osu Keje ọdun 2021.

















