Ọwọ́ tẹ afurasí ajínigbé ọmọ Yorùbá tó n pe ara rẹ̀ ní Fulani àti àwọn mẹ́fà mìí ní Ekiti

Awọn ọlọpaa ati awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, Ekiti state police

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ti ṣafihan ikọ afurasi ajinigbe kan ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa nilu Ado Ekiti.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Sunday Abutu sọ fun awọn akọroyin pe meje ni awọn afurasi naa, ti ọkunrin kan to ti fi igba kan jẹ ọlọpaa ri, Ayo Samuel si wa.

Gẹgẹ bo sẹ sọ ọkunrin mẹfa, obinrin kan lo wa lara wọn.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ni ọwọ kọkọ tẹ mẹrin lara wọn ki ọwọ to tun tẹ awọn mẹta yooku lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla nilu Ilorin,nipinlẹ Kwara.

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ ninu atẹjade to fi sita pe wọn jẹwọ pe awọn lo ji ọkunrin kan, oloogbe Ayeni Abiodun gbe, amọ to bẹ jade ninu ọkọ wọn loju popo, to si pada ku nileewosan.

Awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, Ekiti state police

Bakan naa lo ni ẹnikan lara wọn, Johnson Apotire jẹwọ pe oun ma n dibọn bi Fulani darandaran nitori pe irisi rẹ jọ Fulani.

Ẹwẹ, Ọgbẹni Abutu sọ pe ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ ologun, Amotekun, NSCDC to fi mọ awọn ọlọdẹ ibilẹ, lo mu ki ọwọ tẹ wọn.