Ho-Fiave murder: Ọlọ́pàá Ghana ti ń wá okùnrin tó gbé òkú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ sínú fííjì lẹ́yìn tó gbẹ̀mí rẹ̀ tán

Oríṣun àwòrán, Ghana Police
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Ghana ti tẹ okunrin kan to pa ọrẹbinri rẹ, to si gbe oku obinrin naa sinu firiji ninu lagbege Ho-Fiave.
Igbesẹ naa waye lẹyin ti awọn eeyan adugbo ke gbajere si ileeṣẹ ọlọpaa naa pe awọn n gbọ oorun buburu kan to n jade lati inu ile okunrin naa.
Awọn eeyan naa ni ọpọ ilefo wa loju ferese okunrin ọhun, eyii to mu ki wọn fi agigi ja ilẹkun rẹ.
- "Akẹ́kọ̀ọ́ 1,440 ní iléẹ̀kọ́ 25 ni àwọn agbébọn ti jígbè lọ ní Naijiria"
- Ọdún tó ń bọ̀ ni okọ̀ òfúrufú ‘Air Nigeria’ yóò gbérasọ
- "Lẹ́yìn ti mo lo ọdún 42 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n tú mi sílẹ̀ pé ń kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn"
- Malawi kọ lẹ́tà sí Mike Tyson pé kó di asojú wọn fún ewé ọlà, igbó
- Àlàyé ọlọ́pàá Osun rèé lórí ọ̀nà tí Rahmon Adedoyin gbà ká ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínu fọ́nrán ohùn tó lu ayélujára pa
- Èèmọ̀! Bíṣọ́ọ́bù bá ọmọ tuntun lórí pẹpẹ ṣọ́ọ̀ṣì, láì mọ ẹni tó ni
- Bàbá mi máa ń sunkún torí bí kò ṣe le padà ṣeré tíátà mọ́ - Ọmọ Baba Suwe
- Clem Ohameze, òṣèré tíátà ní àìlera, ó ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà lórí iṣẹ́ abẹ
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Ẹ màá múra sílẹ̀ láti ra lítà epo kan ní ₦320 sí ₦340 lọ́dún 2022- NNPC
- Tówẹ́ẹ̀lì ni bàbá mi ró mọ́ ìdí nígbà tí àwọn sọ́jà wọlé mu lọ - Ọmọ Akintunde
Lẹyin ti wọn ja ilẹkun naa tan ni wọn ba oku ọrẹbinrin rẹ ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Lizzy ninu firiji, ṣugbọn okunrin naa ti na papa bora.
Awọn alabade awọn ololufẹ naa ni iṣẹlẹ naa jẹ kayeefi fun awọn nitori awọn mejeji maa n fi ifẹ han si ara wọn gidi.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, nigba mii wọn maa n pọn ara wọn sẹyin bii ikoko.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn alabage ọhun, Mathias Adogble sọ fun awọn akọroyin pe iṣesi afurasi naa yatọ lẹnu ọjọ diẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
O ni "A fura pe afurasi bẹrẹ si n da irungbọn rẹ si, eyii ti kii ṣe tẹlẹ."
"A tun ṣakiyesi pe o maa n ki gbogbo ara ile tẹlẹ to ba n ti ode bọ, ṣugbọn lẹnu ọjọ meta yii ni kii ki awọn ara ile mọ."
Awọn alabagbe ọhun ni awọn ko le sọ ni pato akoko ti afurasi naa pa ọrẹbinrinrẹ, ṣugbọn ninu iwoye awọn, ko tii ju bi ọsẹ kan lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lagbabe Volta Refional, ASP Efia Tenge sọ pe awọn ti gbe oku obinrin naa lọ sile igbokupamọsi, iwadii si ti bẹrẹ.














