Air Nigeria: Ìjọba ti buwóluu Oṣù Kẹ́rin, ọdún 2022 fún ọkọ̀ òfúrufú ‘Air Nigeria’ láti gbérasọ

Air Nigeria

Oríṣun àwòrán, others

Minisita fun ọrọ irinna ọkọ ofurufu, Sẹnatọ Hadi Sirika ti kede pe Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni ọkọ ofurufu ti orilẹede Naijiria, Air Nigeria yoo gberasọ.

Sirika sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ileeṣẹ ijọba, Presidential villa ni ilu Abuja.

O ni igbimọ alabaṣiṣẹ aarẹ, Federal Executive Council ti Aarẹ Buhari ṣe adari fun ni wọn buwọlu igbesẹ naa lasiko ipade wọn ni Ọjọoru, ni ilu Abuja.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa to ba gberasọ yoo fun ijọba ni ida marun un ipa ninu ileeṣẹ naa, nigba ti awọn oniṣowo aladani yoo ko ipa mẹrindinlaadọta.

O fikun pe ida mẹrindinlaadọta yoo si jẹ fun awọn ti ijọba ri pe wọn kunjuwọn to, to fi mọ awọn oludokowo lati ilẹ okeere.

Minisita fun eto irinna ọkọ ofurufu naa ni o kere tan ileeṣẹ ọkọ ofurufu Air Nigeria naa yoo pese iṣẹ to to ẹgbẹrun lọna aadọrin fun awọn ọmọ Naijiria.

Bakan naa ni Sirika fikun un pe igba kẹfa ni yii ti wọn n jiroro lori ọrọ ''Air Nigeria'' pẹlu Aarẹ Buhari lasiko ipade igbimọ amuṣẹya ijọba apapọ.

Ọdun 2018 ni Sirika kọkọ le pe awọ ti so ileeṣẹ ọkọ ofurugu ti orilẹ-ede Naijiria naa ro.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán