Ojisẹ Ọlọ́run fún osere tíátà ni ₦8m láti ṣiṣẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, prophet Jeremiah Omoto Fufeyin ministries
Yoruba ni ori ẹni nii gbe alawo rere ko ni, bi ori ba si pẹ nilẹ, yoo di ire ni.
Bi ọrọ se jẹ ree pẹlu osere tiata kan, Clem Ohamese ẹni to ri aanu miliọnu mẹjọ naira gba lati ọwọ ojisẹ Ọlọrun kan.
Bẹẹ ba gbagbe, BBC Yoruba ti kọkọ mu iroyin wa fun yin saaju nipa Ohamese to kede pe oun fẹ sisẹ abẹ nitori pe oun ko le rin daadaa.
- Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé bàálù àwọn èèyàn jàǹkàn 91, wọ́n ni wọn ò san owó orí ẹ̀
- Àwọn agbébọn tó yabo ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Jos há síbẹ̀ lẹ́yìn tí agbófinró yí wọn ká
- Àwọn àjòjì ṣá obìnrin tó ń lọ gbálẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Deeper Life pa, ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ara rẹ̀
- Wo ọ̀ná tí àwọn ọkùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù lásìkò ìbálòpọ̀
O ni ijamba ọkọ ti oun ni, lo ti se akoba fun awọn ọmọ ika ẹsẹ oun, tawọn dokita si ni oun nilo isẹ abẹ, ko to di pe oun yoo le rin daadaa.

Oríṣun àwòrán, prophet Jeremiah Omoto Fufeyin ministries
Ìdí sì rèé tí Clem Ohamese ṣe gbé fídíò kan síta pé òun fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ, kí àwọn èèyàn gbà àdúrà fún òun.
Fídíò yìí ni ọkàn lára àwọn gbajugbaja ojisẹ Ọlọ́run kan, Wolii Jeremiah Omotofufeyin ri, to ṣe na ọwọ aanu si osere tiata naa.
Wolii Omotofufeyin gbe ẹ̀bùn Milíọ̀nù mẹ́jọ náírà fún Clem Ohamese láti fi ṣiṣẹ abẹ ọhun.
Ẹ̀bùn owó náà, to jẹ kikida beba sì ni wòlíì Omotofufeyin gbé kalẹ lásìkò ìsìn tó wáyé nínú ìjọ rẹ lọ́jọ́ Aiku níbi tó ti fún osere tíátà náà ni owo beba.

Oríṣun àwòrán, prophet Jeremiah Omoto Fufeyin ministries
Clem Ohameze, òṣèré tíátà ní àìlera, ó ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà lórí iṣẹ́ abẹ

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
O kere o pọ, ki Eleduwa ma jẹ ki aisan ṣe wa, ko ma ṣe ẹni ti a mọ.
Gbajugbaja osẹre tiata Nollywood, Clem Ohameze lo n bẹbẹ adura lọwọ awọn ọmọ Naijiria bi o ti fẹ lọ fun iṣẹ abẹ ẹyin rẹ.
Ohameze ṣalaye ninu fidio kan ti o fi si ori ayelujara, lo ti sọ pe oun fi eegun ẹyin ṣeṣe ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ si oun.
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
- Wọ́n ní ajé wà lárá ọkọ mi ní wọ́n ṣe lò ó - Opó Timothy Adegoke gbarata
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
- Ṣé lóòtọ́ ni àjọ EFCC mú Femi Fani-Kayode?
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Bí àyẹ̀wò òkú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU tó kú sílé ìtura, ṣe wáyé rèé
O sọ pe ijamba ọkọ naa ti oun fi ẹyin ṣeṣe lawọn dokita sọ fun oun pe o ti ṣakoba fun ẹsẹ oun.
Eyi ni ko le jẹ ki o le rin bayii, ṣugbọn pẹlu iṣẹ abẹ ti o fẹ ṣe, o yẹ ki ara rẹ le pada bọ sipo.
Amọ, o sọ ninu fidio to fi lede lori ayelujara pe iṣẹ abẹ ọhun n ba oun lẹru.
''Mo nilo iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria nipa adura bi mo ṣe n lọ fun iṣẹ abẹ yii.
Ayẹwo ti wọn ṣe fun mi lẹyin ti ijamba ọkọ ṣẹlẹ si mi tan, lo fihan pe koko eegun kan ninu eegun ẹyin mi ti yẹ le omiran.
Eleyii lo mu ki ẹru pọ lori eegun ẹyin mi ti ko si le jẹ ki n rin.
Wọn tọju mi fun igba diẹ, mo gbadun diẹ, ṣugbọn laipẹ si akoko yii mo ṣe akiyesi pe mo n ni inira ti mo ba ti n rin.
Mo pada lọ si ile iwosan nibi ti mo ti ṣe ayẹwo MRI lori ẹyin mi.
Lẹyin ayẹwo yii ni awọn dokita sọ fun mi pe mo nilo iṣẹ abẹ lati ya koko eegun ẹyin mi meji to wa lori ara wọn ki n le maa rin daadaa.
Ṣugbọn ẹru ba mi nigba ti wọn sọ fun mi ọna ti wọn maa n gba ṣe iṣẹ abẹ naa.
Wọn ṣalaye fun mi pe wọn maa ni lati la ọrun mu lẹyin ki wọn lanfani lati ya koko egungun to sun lera wọn sọtọ.
Amọ, bi ọjọ ṣe n gori ọjọ, mo ri pe ara inira naa n pọ si fun mi lati rin.
Lẹyin naa ni mo pinnu lati ṣe iṣẹ abẹ ti wọn sọ yii ki n le maa rin pada.
Ọkan mi daru gan an, ailera mi yii si ti ṣakoba iṣẹ mi ni gbogbo ọna.
Loṣu to n bọ ni mo maa lọ fun iṣẹ abẹ yii, mo si mọ pe adura yii yoo gba lori mi, Ọlọrun yoo si ko mi yọ,'' Ohameze lo ṣalaye bẹẹ.



















