Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán
Akẹkọọ to n wa imọ kun imọ ni fasiti OAU ni Ile Ife ni Timothy Adegoke, idanwo si lo lọ se to fi duro sile itura Hilton to wa nilu naa.
Amọ lẹyin ọjọ diẹ lo di awati, ki wọn to wa ri oku rẹ lẹba ile itura naa, ti awọn ọlọpaa si ti ko awọn afurasi to jẹ osisẹ ile itura naa si ahamọ.
Koda, ẹni to ni ile itura naa, Ramon Adedoyin gan wa ni ahamọ ọlọpaa, ti iwadi si ti n lọ lọwọ.
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
Nigba ti BBC Yoruba de ilu Eruwa, tii se ilu abinibi oloogbe Adegoke, se ni awọn obi rẹ, ọmọ aya atawọn aburo rẹ n wa ẹkun mu.
Ninu ọrọ rẹ, aya oloogbe salaye bi ọkọ rẹ se rin, to fi se agbako iku ojiji, to si ni oun gbọ pe wọn ri aje lara ọkọ oun ni wọn se lo o.
Bakan naa ni awọn obi Timothy ni ogo idile awọn ni ọkunrin naa jẹ, iku rẹ ko si gbọdọ ja sasan, gbogbo ẹni to ba si lọwọ ninu dida ẹmi rẹ legbodo, ni ko gba idajọ to yẹ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ naa, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola tako ọpọ ahesọ ọrọ to n lọ lori iku oloogbe naa lori ayelujara.
Opalola ni irọ to jinna sootọ ni pe wọn pa Timothy Adegoke lati fi se etutu ni nitori o ni ẹyin ara oloogbe naa kankan ko di awati lara rẹ.
- Òbí mẹ́ta ń banújẹ́ torí bí ọlọ́pàá ṣe gbé àwọn ọmọ wọn tó kópa nínú ìwọ́de EndSARS pamọ́ láti ọdún kan sẹ́yìn
- 'Búrẹ́dì ni ọkọ mi lọ rà fún ọmọ wa ti wọ́n fi sá a pa tí mo di òpó lọ́jọ́ orí kékeré'
- Ẹkún gbígbóná lójú abiyamọ! bàbá Itunu Babalola barajẹ́ lórí ọmọ rẹ̀ tó kú sí ẹ̀wọ̀n ní Côte d'Ivoire
- 'Tí wọ́n bá bá ẹ sùn tí wọn ò "release" wọ́n á gba owó wọn, àwa la ń ra Kọ́ńdọ́ọ̀mù tí wọ́n fi ń bá wa sùn ní Mali'
- Ìtàn ''Freedom Park'' ní Eko rèé níbi tí àwọn òkú àti àlùjànú tí wá ń wo ''show''




