Itunu Babalọla Death: Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

Baba Itunu Babalọla,Abayomi ko le e pa ibanujẹ rẹ mọra lasiko to n sọ ohun ti oju ọmọ rẹ ri ni ọgba ẹwọn ti wọn fi si ni orilẹede Côte d'Ivoire ko to di oloogbe.

Baba rẹ ṣe apejuwe ọmọ rẹ gẹgẹ bi ẹni to n pese ounjẹ oojọ fun awọn nitori iya rẹ wa lori idubulẹ aisan.

''Ọdun 2019 to wa si ile lati wa ba wa se ọdun ni ekeji rẹ ti wọn jọ n gbe ile pe e pe ole jawọ ile wọn, pe ko si ma a pada bọ.''

BBC Yoruba kan si Arabinrin Abike Dabiri to jẹ adari ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọm Naijiria to wa lẹyin odi lori bi baba Itun ṣe n beeere fun oku ọmọ rẹ yii, esi to fun wa wa ninu ọrọ ori foonu to ba wa sọ yii : Èsì ìjọba Naijiria rèé sí Baba Itunu Babalola tó ń béèrè fún òkú ọmọ rẹ̀ àti irú ikú tó pa á

Ẹkunrẹrẹ fidio yii sọ bi Itunu Babalola se de ọgba ẹwọn, to si n beerẹ fun idajọ ododo...