Osun, Ekiti guber polls: N22.5m lowó fọ́ọ̀mù àti díje fún ipò gómìnà lẹ́gbẹ́ APC

Oríṣun àwòrán, @Pristinenetwor1
Ẹgbẹ oṣelu APC ti kede miliọnu mejilelogun ati abọ gẹgẹ bi owo fọọmu fawọn to ba fẹ dije fun ipo gomina nipinlẹ Osun ati Ekiti lọdun 2022.
APC tun kede ọjọ kejilelogun oṣù kinni ọdun 2022 ati ọjọ karun un oṣu kẹta gẹgẹ bi ọjọ ti idibo abẹle yoo waye l'awọn ipinlẹ mejeeji.
Lọjọ Aiku to lọ ni APC kede pe oun yoo bẹrẹ si ni ta fọọmu fawọn oludije ibo Gomina nipinlẹ Osun ati Ekiti.
Ajọ eleto idibo INEC ti kọkọ kede ọjọ kejidinlogun oṣu kẹfa ọdun 2022 gẹgẹ bi ọjọ ti ibo gomina yoo waye nipinlẹ Ekiti.
Bakan naa ni INEC kede ọjọ kerindinlogun oṣu keje gẹgẹ bi ọjọ ibo gomina nipinlẹ Osun.
Gẹgẹ bi o ti ṣe ninu eto idibo gomina ipinlẹ Anambra, adele akọwe ẹgbẹ APC, John Akpanudoedehe ṣalaye pe N2.5m wa fun erongba awọn oludije lati dupo gomina nigba ti N20m jẹ owo fọọmu ati dije.
- ₦22.5M ti pọ̀ jù fún owó fọ́ọ̀mù ìdìbò abẹ́lẹ́ sípò gómìnà APC - SERAP
- Owó fọ́ọ̀mù APC fún ipò Ààrẹ pọ̀jù- olùdíje
- Ọnà ayédèrú ní wọn gbà gbé àbájáde ìwádìí Endsars tàwọn èèyàn n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jáde - Ọgágun Irabor
- 'Irọ́ ńlá lẹ pa, Lai Mohammed ò kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate'
- Òhun tí Cute Abiola ṣe rèé táa fí sọ ọ́ sí àhámọ́ - Iléeṣẹ́ Navy
Amọ, ẹgbẹ APC sọ pe awọn oludije obinrin at'awọn to ba ni ipenija ara le san idaji owo yii.
Ọjọ kọkanla oṣu kinni ọdun 2022 ati ọjọ kejidinlogun oṣu keji ni o jẹ gbedeke fawọn oludije lati fi fọọmu idije ti wọn ba ra ranṣẹ si ẹgbẹ.
Lẹyin ọjọ mẹta si mẹrin ti wọn ba ti fi fọọmu naa ṣọwọ sí ẹgbẹ ni ayẹwo awọn oludije yoo waye.
Lọjọ kẹtadinlogun ati kokandinlogun oṣu kinni ọdun 2022 ni ẹni to ba fẹ pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ibo abẹle gomina ipinlẹ Ekiti lanfaani lati ṣe bẹẹ.
Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kinni ati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keji ọdun 2022 l'awọn to ba fẹ pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idibo abẹle gomina ipinle Osun lanfaani lati ṣe bẹẹ.

















