Akeredolu appoints Son: Kò sí nkan tó burú nínú bí Akeredolu ṣe yan ọmọ rẹ̀ sí ipò - Agbẹnusọ

Akeredolu ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Onimọ nipa eto oselu, Yemi Fash ti ni ko lodi si ofin lorilẹede Naijiria lati yan mọlẹbi si ipo amọ ohun to tọ ni lati mọ boya ẹni ti wọn yan si ipo naa kunjuwọn abi bẹẹ kọ.

Eyi ko ṣẹyin bi Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ṣe yan ọmọ rẹ ọkunrin, Babajide Akeredolu si ipo gẹgẹbi alaga ajọ to n risi iṣẹ akanṣẹ nipinlẹ Ondo (DG PPIMU).

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu igbese gomina naa, amọ ninu esi ti agbẹnusọ fun gomina Akeredolu, Richard Olabode fi lede lo ti sọ pe ko si ohun to buru nibẹ nitori aye n ṣe iru rẹ.

Àkọlé fídíò, Ọdún 1999 ni mo tí ń gbìyànjú láti gba SAN kí wọ́n tó fún mí ẹ̀ní ọdún 90 -Toriola Oyewo

Amọ onimọ nipa eto oṣelu Yemi Fash lasiko to n sọrọ ni ẹnikẹni ti awọn eniyan ba dibo yan amọ to fi ọmọ rẹ tabi mọlẹbi rẹ si ipo gbọdọ fun awọn araalu ni aridaju pe ẹni ti o yan si ipo naa kunjuwọn lai kii ṣe pe o kan yan an si ipo.

''Mi o ro pe o lodi si ofin lati yan mọlẹbi si ipo, to ba jẹ pe o lodi si ofin ni iba buru jai.''

''Amọ ẹnikẹni to ba fi molẹbi rẹ si ipo gbọdọ jẹ ki awọn araalu mọ wi pe mọlẹbi naa kunjuwọn lo ṣe wa ni ipo naa,''

''Nitori a ri awọn araalu to le e ṣe ju mọlẹbi naa lọ to yẹ ki o di ipo naa mu.''

Lori ọmọ gomina Akeredolu ti wọn yan si ipo naa, gbogbo eniyan ni wọn ma n sọ wi pe oun ṣiṣẹ takuntakun, to si ti n ran baba rẹ lọwọ lati igba to ti de ipo''

''Ko ṣẹṣẹ ma aṣiṣẹ takuntakun ti wọn tilẹ fi ẹsun kan an wi pe oun lo n ṣe ijọba baba rẹ lai si ni ipo kankan.''

''Nitori naa bi o ṣe wa ni ipo yii, yoo le e sise lọna to ba ofin mu.''

Bakan naa ni onimọ nipa eto oṣelu naa fikun pe ki o ṣiṣẹ ni ijọba baba rẹ dara ju ki awọn ọmọ gomina miran ti wọn yoo ba na owo ilu basubasu tabi ki wọn ma a lọ si oke okun bi ẹni lọ si ọja.

Akeredolu ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu

'Kò sí nkan tó burú nínú bí Akeredolu ṣe yan ọmọ rẹ̀ sí ipò! Ayé ń ṣe irú ẹ̀'

Akọ̀wé iroyin fun gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, Richard Olabode, ti sọ pe ko si nkan to buru tabi ti oju ko ri ri ninu bi gomina ṣe yan ọmọ rẹ si ipo.

Ninu atẹjade kan lo ti sọ bẹẹ.

Ọjọ́ Iṣẹgun ni Gomina Akeredolu gbe orúkọ àwọn kọmisanna rẹ tuntun ati awọn oludari ileeṣẹ ijoba lọ si ile asofin ipinle naa.

Lara wọn si ni ọmọ rẹ ọkùnrin, Babajide Akeredolu to yan gẹgẹ bii Oludari àjọ ti yoo maa n mojuto, ti yoo si maa tọ pinpin awọn àkànṣe isẹ ti ìjọba ba n gbe.

Iyansipo rẹ waye leyin ọpọlọpọ oṣù ti Gomina Akeredolu sọ pe ko si nkan ti ẹnikẹ́ni le ṣe si, ti oun ba pinnu lati yan ọmọ naa si ipo.

O ni ọmọ oun ṣíṣẹ karakara lasiko ìpolongo ibo to gbe oun wọlé.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ọkùnrin mẹ́tà ló timi mọ́lé tí wọ́n n bá mi sùn lójoojúmọ́ ni Libya

Níbi apejẹ kan to fi ṣe ayẹyẹ ọdun kẹta rẹ ni saa akọkọ lọ́dún 2020.O ni ọmọ ipinlẹ Ondo ni Babajide, to si tọ sii lati di ipo mu. Ni bayii ti Akeredolu ti yan ọmọ rẹ si ipo, Akọwe rẹ, Richard Olabode sọ pe kii ṣe oun ni yoo kọ́kọ́ ṣe iru nkan bẹẹ. O ni awọn gomina bi Jonah Jang ti ipinlẹ Plateau, gomina tẹlẹ ni Imo, Rochas Okorocha, Tanko Al-Makura ti Nasarawa, to fi mọ gomina tẹ́lẹ̀ nipinlẹ Ondo, Olusegun Mimiko, lo ti yan ọmọ tabi ẹbi wọn ri si ipo.