2023 Election: Akeredolu ní ààrẹ́ Buhari ti ṣe ọdún mẹ́jọ, ìha Gusu ló kàn

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu kankan to ba mu aarẹ lati ariwa orilẹ-ede Niajiria ni idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023 yoo kuna atilẹyin awọn ara Guusu.
Akeredolu sọ eyi lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels Television.
Lasiko ti gomina Akeredolu n sọrọ, o ni awọn gomina labẹ asia Ajọ awọn gomina ni iha Guusu Naijiria ti panupọ sọ pe iha Guusu Naijiria ni aarẹ ti gbọdọ wa ni ọdun 2023.
- Ayo Ewebiyi Mama Oriki: Ọwọ́ Òbí, Ìjọba àti àwọn Ọba ni ìdágbàsókè Yorùbá wà lásìkò yìí
- Ẹ san N20bn náà fún Igboho kíákíá; Dáa padà! Ìjọba àpapọ̀ jùú sí ẹgbẹ́ Ilana Ọmọ Oodua
- Ojú ọjọ́ gbìgbóná jànyinjànyin ti kọjá kèrémí káàkiri àgbáyé
- Ọkùnrin kan dèrò àtìmọ́lé ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ewúrẹ́
- Yorùbá ẹ fura o! Ìwẹ̀fá ìjọba àpapọ̀ gbáà ní Fani-Kayode tó ń díbọ́n bí ọ̀kan lára wa
O ni igbeṣẹ yii lo ba ọna ododo ati ẹtọ mu ni awujọ.
Gomina ipinlẹ Ondo ni aarẹ Muhammadu Buhari to wa lati ariwa orilẹ-ede Naijiria ti ṣe ọdun mẹjọ, ti yoo si pari ọdun 2023, ohun to tọ lẹyin eyi ni ki aarẹ wa lati Guusu.
''Ẹgbẹ oṣelu mẹta lo wa ni Ajọ Southern Governor's Forum, awọn ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Grand Alliance (APGA), Peoples Democratic Party (PDP) ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).
Ohun ti a gbagbọ ni pe ẹgbẹ oṣelu to ba mu ẹnikẹni lati iha ariwa orilẹede Naijiria ko le e ri atilẹyin awọn gomina ati awọn eniyan ara agbegbe naa.''

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Facebook
''Bio tilẹ jẹpe ajọ awọn gomina kii ṣe ẹgbẹ oṣelu, ohun ti a n pe fun ni ki a yi ipo aarẹ wa si guusu orilẹede Naijiria.''
''Ohun ti o tọ, ti o si dara ni ki a yi ipo aarẹ wa si guusu nigba to jẹ wi pe iha ariwa lo ti wa ni ipo fun ọdun mẹjọ bayii.''
- Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni yóò parí ọ̀rọ̀ yìí -Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà
- Wo ìlú tó fẹ́ sọ àdúgbò kan lórúkọ aṣẹ́wó ọmọ Nàìjíríà, Eunice Osayande tí wọ́n pa
- Banki àpapọ̀ Nàìjíría ti pasẹ titi ojú òpó Aboki FX pa
- Ìyanṣẹ́lódì míràn kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ àyàfi tí Ijọba àpapọ̀ bá....- ASUU
- Kí ẹnikẹ́ni má gbé ìyá mi síta mọ́, mí o ní agbẹnusọ kankan mọ́- Sunday Igboho
Akeredolu nigba to n fesi si ọrọ awọn to ni ẹni to kunjuwọn lo yẹ ko jẹ aarẹ ko niiṣe pẹlu iha to ti wa, ni gbogbo iha ati ẹya to wa ni Naijiria lo ni awọn eniyan to kunjuwọn.
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ni ọpọlọpọ eniyan lo kunjuwọn lati di ipo aarẹ mu, ati pe bo ṣe wa ni iha Guusu Naijiria naa lo wa ni ariwa, nitori naa ko si ibi tabi ẹya ti gomina ko tii le wa.
















