Bestiality: Ọkùnrin kan dèrò àtìmọ́lé ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ewúrẹ́

GORSE HILL CITY FARM

Oríṣun àwòrán, Ewurẹ

Aye ti wa di oju keji bayii o. Ọkunrin kan, ẹni ọdun marundinlọgbọn, Nasiru Muhammad ti dero atimọle ọlọpaa lori ẹsun pe o ni ibalopọ pẹlu ewurẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa, ASP Lawan Shiisu ṣalaye pe ni ijọba ibilẹ Gwaram ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

ASP Shiisu ṣalaye pe nigba tawọn ọlọpaa n kaakiri ilu Gwaram ni ọwọ tẹ Muhammad lagbegbe Kunnadi.

''Ni ọjọ kẹsan an oṣu kẹsan an ọdun 2021 lawọn ọlọpaa ri ọmọkunrin ọdun mẹẹdọgbọn yii nibi ti o ti n ba ewurẹ sun.

Nibẹ naa ni awọn ọlọpaa ti fi ọwọ ofin mu un.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Muhammad wa ni atimọle ọlọpaa bayii nigba ti iwadii si n lọ lọwọ lori ọrọ naa.

Ọkunrin naa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori iṣẹlẹ ọhun,'' agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni