Yoruba Nation: Ẹ má da ẹnikẹ́ni tó bá ní pé òun ni agbẹnusọ mi lóhùn mọ́- Sunday Adeyemo Igboho

Oríṣun àwòrán, @Igboho
Ajijangbara kan lara awọn to n beere fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Yoruba Nation ti sọrọsoke.
Oloye Sunday Igboho ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho lo fi ohun ranṣẹ si awon eeyan rẹ lati ahamọ to wa ni Cotonou.
Igboho ni oun ko ni agbenuso kankan mọ ati pe ki ẹnikẹni ma pe ara rẹ ni agbẹnusọ oun.
Bakan naa lo ni ki wọn ma gbe iya oun, iya oosa sita mọ nitori pe ọtọ ni aaye abiyamọ.
- Wo ìlú tó fẹ́ sọ àdúgbò kan lórúkọ aṣẹ́wó ọmọ Yorùbá, Eunice Osayande tí wọ́n pa
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- Agbẹnusọ àjọ EFCC Wilson Uwujaren ti ṣàlàyé nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gá àjọ náà lósàn ọjọ́bọ
- ECOWAS f'òfin de àwọn ológun tó dìtẹ̀ gbàjọba ní Guinea
- Lónìí ni ìdájọ́ yóò wáyé lórí N500m tí Sunday Igboho bèèré lẹ́yìn ìkọlù DSS sílé rẹ̀
Agbẹjọro Yomi Aliyu lo ba Sunday Igboho fi at\rjade naa sita.
Ọgbẹ́ni Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mọ si Sunday Igboho ti kilọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe iwọde ifẹhonuhan kankan ni orukọ oun.
O sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to gba ọwọ agbẹjọro rẹ̀, Yomi Aliyu jade.
Igboho to n ja fun ominira iran Yoruba, ni wọn mu ni orilede Cotonu loṣu diẹ sẹyin lasiko to n lọ si orilede Germany.
- Ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí mi láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Femi Fani-Kayode
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- A kò mọ̀ọ́mọ̀, bàálù ìjagun tó pa àwọn eèyàn Yobe náà ṣèèṣì jábọ́ ni- Iléeṣẹ́ Ológun Nàìjíríà
- Nkechi Blessing ò lè fẹ̀sùn ibálòpọ̀ láti gba "role" kàn mí láyé! Tó bá dán an wo... - Damola Olatunji
- Àwọn jàndùkú jí Emir Bungudu gbé, wọ́n pa ọlọ́pàá lọ́nà mọ́rosẹ̀ Abuja sí Kaduna
Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn kankan ní orúkọ mi- Sunday Igboho
Sunday Igboho kìlọ̀ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ní orúkọ òun
Agbẹjọro Igboho Yomi Aliyu ninu atẹjade to fi sita ni Ọjọbọ ṣalàye pe Igboho ti paa lasẹ fun oun pe ko si énikẹni to gbọdọ jade ifẹhonuhan nitori oun tabi ni orukọ oun.
Bakan naa lo fi kun pe ko si éni to gbọdọ kọlu awọn nnkan ini ijọba, ara ilu tabi awọn eleto aabo labẹ ẹtan pe wọn n ja fún Yoruba Nation.

Oríṣun àwòrán, Igboho
Yomi ni: Gbogbo nkan ni asiko wa fun. Oloye Sunday Adeyemo n bọwọ fun awọn eniyan ti ajọ DSS pa nile rẹ lọjọ kini osu keje ọdun yii."
" Nitori idi yii, o ti kede pe ẹnikẹni ko gbọdọ wọde ifẹhonuhan nitori oun"
" Bakan naa lo fi kun pe, oun fẹ ki awọn eniyan bọwọ fun awọn ẹbi oun gidigidi paapaa julọ awọn to n pe iya oun pe ki o yọju si gbangba.
O ni Igboho ko ni agbẹnusọ kankan nibikibi ni asiko yii.
" Ẹ jẹ ki a bọwọ fún awọn ti o ti ku, kí ẹnikẹni maa lọ maa kọlu nnkan ini ijọba labẹ pe awọn n ja fun Yoruba Nation.



















