Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run

Kayeefi ni ọrọ yii jẹ fun ọpọlọpọ eeyan to ti gbọ nipa rẹ o.
Ọkunrin kan lo dero ọrun lẹyin to lẹ ''super glue'' oko rẹ nigba to gbagbe rọba idaabobo ṣaaju ibalopọ pẹlu ọrẹbinrin rẹ ti jẹ Ọlọrun nipe.
Salman Mirza, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ni iroyin sọ pe o lẹ ''super glue'' mọ nkan ọmọkunrin rẹ lati le dena oyun nigba ti o fẹ ni ablopọ pẹlu ọrẹbinrin rẹ nile itura kan niluu Gujarat lorilẹede India.
- Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí
- Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Ọ̀gá ọlọ́pàá Èkó kàn sí ẹbí Monsurat tí ọlọ́pàá yìnbon lù
- Lóòtọ́ ni ìyá yìí bímọ méjì fún ọmọ rẹ̀ tó ń bá sùn, ohun tí a ṣe síi rèé - Àjọ NSCDC Kwara
Oun ati ololufẹ rẹ ni a gbọ pe wọn lo oogun oloro ki wọn ba le lagbara fun ibalopọ gbankọgbi ti wọn fẹ ṣe nile itura.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Mirza ni wọn ba ni ita ile itura naa ni ọjọ keji.
Ọga ọlọpaa niluu Ahmedabad ṣalaye pe awọn mejeeji tun fin awọn oogun oloro mii si imu ki wọn to bẹrẹ ibalopọ wọn.
Ọpọ eeyan ni adugbo ni wọn jẹri pe awọn mejeeji maa n ṣaaba lo oogun oloro papọ.
Nigba ti wọn ri Mirza nibi to wa ni ita ni wọn gbe e digba digba lọ si ile ile iwosan.
Amọ, ọwọ ti bọ sori, ile iwosan yii naa ni o ti dagbere faye.
Awọn ẹbi Mirza pe fun iwadii lori ohun to pa ọmọ wọn.
Ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to pa ọmọkunrin yii gan an, o ni esi maa to jade laipẹ.
- Wo ọ̀nà méje tí o lè fi dáàbò bò ọmọ rẹ níbàyìí tí iléẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ padà
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
- Femi Ojudu faṣọ iyí mọ́ Kayode Fayemi lára, Ó ní ojú ń gba òun ti fún ipò táwọn títì Ekiti wà
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- Àwa ọmọ Iyabo Oko ló dá owó gọbọi fi gbé ìyá wa lọ sí India fún ìtọjú- Ewa, ọmọ Iyabo Oko
















