Masquerade vs muslims: Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì dèrò àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí

Oríṣun àwòrán, NAIJ.com
Ile ẹjọ giga ilu Osogbo ti ju atọkun eegun, Oloye Kayode Esuleke, ọmọkunrin rẹ ati eeyan meji si atimọle lori ẹsun ni mọṣalaaṣi.
Adajọ Ayo Oyebiyi paṣẹ pe ki wọn gbe wọn lọ si ọgba ẹwọn to wa niluu Ilesha lọjọ Iṣẹgun.
Oloye Esuleke, Kola Adeosun, Akeem Idowu, ati Ifasola Esuleke lo n jẹjọ lori ẹsun ipaniyan onikoko mẹtala to da lori ibankanjẹ, dida alaafia ilu ru ati jagidijagan.
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
- Akeredolu yan Deji Akure gẹ́gẹ́ bi alága ìgbìmọ̀ àwọn ọba ni Ondo
- EFCC mú àwọn gbájúẹ̀ orí ayélujára 56 ni òtẹ́lì àti àwọn bùba mííràn ni ìpińlẹ̀ Ogun
- Wo ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí UAE ń wá lórí ẹ̀sùn ṣíṣe àtìlẹ́yìn owó fún Boko Haram
- Wo bí Pásítọ̀ Adeboye, Wòlíì Iginla ṣe ń dárò ikú akẹgbẹ́ wọn David Yonggi Cho
Amọ gbogbo wọn lo sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Adajọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkanlelogun oṣun kẹsan ọdun 2021 yii.
Ọjọ jọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan an yii ni awọn eleegun atawọn musulumi ni mọṣalaasi Kamorudeen Society to wa ni Oluode Aranyin, Osogbo kọlu ara wọn.
Nibẹ ni a gbọ pe ibọn ti ba Moshood Salawudeen ti o si gba ibẹ dero ọrun nigba ti ọpọ eeyan farapa nibi ikọlu naa.
Iroyin sọ pe wọn tun ba mọṣalaaṣi ọhun jẹ nigba tawọn eleegun naa n kọja lọ.















