Adeboye, Iginla sọ nípa Pastor David Yonggi Cho tó d'olóògbé

Oríṣun àwòrán, Pastor E A Adeboye
Pasitọ to ni ọkan lara awọn ijọ to tobi julọ lagbaye ti di oloogbe.
Oniwaasu naa jẹ olubadasilẹ ijọ Yoido Full Gospel Church Assemblies of God ni orilẹede South Korea.
Cho to jẹ ẹni ọdun 85 jẹ Ọlọrun nipe ni ọjọ Iṣẹgun ọsẹ ninu atẹjade kan to tẹ BBC lọwọ gẹgẹ bi aridaju.

Oríṣun àwòrán, Pastor David Yonggi Cho
Lasiko iku rẹ, Cho n gba itọju lọwọ ni lorii aisan inu ọpọlọ to ti n ba finra lati ọdun 2020.
Awọn gbajugbaja oniwaasu lorilede Naijiria kii ṣai darukọ ati bọwọ fun oniwaasu ilẹ South Korea yii.
Pasitọ Enoch Adeboye ti ijọ Redeemed Christian Church of God (RCCG), Pasitọ Joshua Iginla atawọn mii naa n ṣe idaro rẹ ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Pastor David Yonggi Cho Ministry
Itan nipa David Yonggi Cho
Wọn bii ni ọdun 1936 sinu idile ẹlẹsin Bhuddism kan lasiko ogun Korea.
O yipada si ẹsin Kristẹni nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun eyi si waye lẹyin igba ti awọn dokita sọ fun un pe yoo ti ọwọ aisan ikọ fee buruku ku.
Cho ṣe iṣẹ iranṣẹ loju paali lai ṣe iṣẹ mii to si kawe gboye nile ẹkọ iṣẹ iranṣẹ Full Gospel College lọ̀dun 1956.

Oríṣun àwòrán, Pastor David Yonggi Cho
Lọdun 1958, o ṣi ijọ kekere kan si ilu Seoul eyi to pada di nla to n jẹ Yoido Full Gospel Church.
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun, ijọ yii pada di ọkan lara awọn ijọ nla nla to tun gbajumọ ju lagbaye.
Yoido Cho Full Gospel Church ni ijọ ẹẹdẹgbẹta jakejado South Korea.
Bakan naa wọn ti ran ọgọọrọ awọn ajihinrere lọ si oriṣiriṣi orilede lagbaye. Yoido ni ọmọ ijọ to le ni miliọnu ẹẹdẹgbẹrin ati abọ.
Cho ti kọ ọpọlọpọ iwe koda o tun ṣe idasilẹ iwe iroyin olojoojumọ, o da ajọ ẹlẹyinju aanu silẹ, eyi ni ijọ rẹ sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita.
Iyawo Cho ni tirẹ jade laye ninu oṣu keji ọdun yii wọn si jọ ni ọmọkunrin mẹta papọ.

Oríṣun àwòrán, Screengrab/Facebook
Ohun ti Pasitọ Adeboye ati Iginla sọ nipa Oniwaasu Yonggi Cho
Awọn agba oniwaasu ni Naijiria ti bẹrẹ si ni sọ nipa iku Pasitọ David Yonggi Cho.
"O tun di igba tao pade lowurọ ọjọ ajinde, sun re niwaju Ọlọrun Pasitọ, Ọmọwe Yonggi".
Eyi ni ọrọ Pasitọ Enoch Adeboye ti ijọ RCCG.
Oniwaasu orilẹede Naijiria mii, Wolii Joshua Iginla sọ pe Yonggi Cho ni "baba oun ninu Oluwa".
Ninu ọr rẹ, Wolii Iginla ṣapejuwe oniwaasu agbaye naa gẹgẹ bi eekan irandiran, afini mọna, eeyan ti Ọlọrun we bii ni ti kii ṣe ẹlẹran ara".














