Yoruba Nation One million man march: Àwọn tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation ní IPOB kò ṣiṣẹ pọ̀ pẹ̀lú àwọn

Oríṣun àwòrán, @Akintoye
Awọn to n ṣagbatẹru idasilẹ Yoruba nation ti ṣalaye fun ijọba Naijiria pe ẹgbẹ ajijagbara IPOB kọ lo ṣe agbekalẹ ifẹhonuhan tawọn n ṣe ni olu ileeṣẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN lorilẹede Amẹrika.
Eyi ni esi wọn si atẹjade ijọba apapọ to kilọ pe wọn o gbọdọ ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Biafra, IPOB.
- ''APC yóò fún Goodluck Jonathan ní ànfàní láti dupò ààrẹ lọ́dún 2023 tó bá darapọ̀ mọ́ wa''
- Mi ò sọ pé àwọn tó ń pè fún Yorùbá Nation kò yàtọ̀ sí Boko Haram o- Gbajabiamila ṣàlàyé
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- Nkechi Blessing ò lè fẹ̀sùn ibálòpọ̀ láti gba "role" kàn mí láyé! Tó bá dán an wo... - Damola Olatunji
- Iléeṣẹ́ ìjọba, ẹ yé ra ọkọ̀ tòkunbọ̀ fàyàwọ́ mọ́- Ajọ Customs kìlọ̀
- Ẹ̀yin oníṣègùn ìbílẹ̀, ẹ bá wa ṣe àwárí oògùn àjákálẹ̀ àrùn covid-19- Ìjọba Naijiria
Lati ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an ọdun 2021 yii lawọn ajijagbara fun Yoruba Nation atawọn ẹya mii naa ni Naijiria ti n ṣe iwọde ni olu ileeṣẹ ajọ UN niluu New York lorilẹede Amẹrika.
Iwọde yii wa jẹ asiko kan naa pẹlu apejọ ajọ UN nibi ti Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn olori orilẹede agbaye mii yoo ti sọrọ apilẹkọ.
Alaga ẹgbẹ NINAS to jẹ akojọpọ awọn ẹgbẹ ajijagbara ni Naijiria, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni awọn n ṣe iwọde niwaju olu ileeṣẹ ajọ UN lati le jẹki gbogbo aye mọ bi awọn darandaran ṣe n fi ẹmi awọn eeyan ṣofo lapa Guusu ati arin gbungbun orilẹede Naijiria

Yorùbá Nation, yàgò fún IPOB níbi ìwọ́de tó ń lọ lọ́wọ́ ní New York bí bẹ́ẹ̀kọ́....- Ìjọba Buhari
Bí ewúrẹ́ Yorùbá Nation bá bá àgùntàn IPOB rìn ojú kàn náà là ó fí wò yín- Ìjọba Nàìjíríà
Ijoba Naijiria ni idi ti awọn se n lọgun bẹẹ ni pe labẹ ofin awọn ka IPOB gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi to n da omi alafiaa ru.
Ninu atẹjade kan lati ọwọ oludamọran agba si aarẹ, Garba Shehu, o ni IPOB ni to awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun lọna aadọta ọmọ ogun ti rẹ.
O fi kun un pe ko si ẹni ti yoo ka awọn to n beere fun idasilẹ Yoruba Nation kun lopin igba ti wọn ba n ba n ṣe iwọde to mu iwa janduku lọwọ.
- Wo ọ̀nà méje tí o lè fi dáàbò bò ọmọ rẹ níbàyìí tí iléẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ padà
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
- Eèmọ̀ wọ̀lú, ẹni tó ń ta ọtí àti ògógóró gún Oníbárà rẹ̀ pa ní Osun!
- Àwa ọmọ Iyabo Oko ló dá owó gọbọi fi gbé ìyá wa lọ sí India fún ìtọjú- Ewa, ọmọ Iyabo Oko
- ''Ìjọba, ẹ má da àwa tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation pọ mọ IPOB''
Ọrọ́ ileesẹ aarẹ yi ko sẹyin bi awọn ọmọ ikọ IPOB se darapọ mọ awọn ti Yoruba Nation nibi iwọde ranpẹ ti wọn se niwaju ẹgbẹ isọkan agbaye ni New York.
Nibi iwọde yi ni wọn ti fi ẹhonu han lori awọn aiṣedeede to n waye ni Naijiria ati ipe wọn fun idasilẹ orileede Yoruba Nation.
Aarẹ Buhari la gbọ pe yoo kopa laipẹ yi nibi apero ajọ isọkan agbaye.
Agbẹnusọ aarẹ Garba Shehu tutọ soke foju gba ninu atẹjade rẹ to si ni ''iyalẹnu lo jẹ bawọn se ri ti awọn Yoruba Nation ko ṣe bikita lati darapọ mọ ikọ IPOB
O ni ''ṣe IPOB to n da omi alaafia ru lagbegbe rẹ , to n ko awọn araalu ni panpẹ ti wọn si n tẹ ẹtọmọniyan mọlẹ ni ẹ fẹ ki wọn ka yin mọ?''
"Lai si iyemeji, awọn ọmọ Naijiria ati gbogb aye yoo da yin lẹjọ nipa iru awọnti ẹ n kọwọrin pẹlu''.
- Iléeṣẹ́ ìjọba, ẹ yé ra ọkọ̀ tòkunbọ̀ fàyàwọ́ mọ́- Ajọ Customs kìlọ̀
- Eèmọ̀ wọ̀lú, ẹni tó ń ta ọtí àti ògógóró gún Oníbárà rẹ̀ pa ní Osun!
- Wo ọ̀nà méje tí o lè fi dáàbò bò ọmọ rẹ níbàyìí tí iléẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ padà
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
- Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì dèrò àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí
''Ko si ẹni ti yoo ka ẹgbẹ yin kun lopin igba ti ẹ baa n ba IPOB se pọ.Ti awọn alajọṣepọ wọn(IPOB) ba n tẹ ẹtọmọniyan mọlẹ, eyi yoo mu ki ajọ UN gaan foju sunukun wo ifarajin yin si mimu agbega ba afojusun UN''

Oríṣun àwòrán, Ilana omo oodua
Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
Awọn to wa sibẹ wa pẹlu oniruuru patako alakọle lati fi ẹhonu wọn han.
Iwọde onimiliọnu kan eeyan tawọn ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba lawọn yoo ṣe niwaju olu ileeṣẹ ajọ United Nations waye loni bi wọn ṣe ṣeleri.
Amọṣa ohun ti oju BBC News Yoruba to nibẹ ni pe ero ko pọ bi wọn ṣe lero, bẹni awọn to wa wa pẹlu oniruuru patako alakọle lati fi ẹhonu wọn han.
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Wo bí ọlọ́jọ́ ṣe dé fún Ola Ibironke, olówó orí Bimbo Oshin àti ibi tó parí iṣẹ́ sí
- Kókó nǹkan tí ẹgbẹ́ NINAS ń bèrè fún ní ibi ìpàdé UN General Assembly
Ọjọgbọn Banji Akintoye to jẹ aṣiwaju ẹgbẹ to n ja fun idaduro ilẹ Yoruba kede ṣaaju pe iwọde oni miliọnu eeyan yoo waye ni adojukọ olu ileeṣẹ ajọ iṣọkan agbaye, United Nation to wa nilu New York ni Amẹrika laarin ọjọ kẹrinla si ikẹrinlelogun oṣu kẹsan ọdun 2021.

Oríṣun àwòrán, Ilana oodua
Gẹgẹ bi o ṣe sọ iwọde naa wa lati pe akiyesi awọn awujọ agbaye si ipenija to n waye fun awọn ẹya ni Naijiria pẹlu igbenipa to n ṣẹlẹ kaakiri latọwọ awọn darandaran Fulani.
Bakan naa lo ni wọn yoo tun lo iwọde naa lati pe fun akiyesi agbaye lori ikslu awọn akọroyin ati wahala ọrọ abo ti ko gboriduro ni Naijiria.



















