Yoruba Nation: Kókó nǹkan tí ẹgbẹ́ NINAS ń bèrè fún ní ibi ìpàdé UN General Assembly

Yoruba Nation: Kókó nǹkan tí ẹgbẹ́ NINAS ń bèrè fún ni ibi ìpàdé UN General Assembly

Oríṣun àwòrán, Banji Akintoye

Onírúurú àwọn ẹ̀sun ni ẹgbẹ́ NINAS ti fi léde gẹ́gẹ́ bi ìdí tí wan fi n pè fún ìwọ́detí yóò wáye ni New York lórílẹ̀-èdè America.

Lára àwọn nǹkan tí wọ́n ń pè fún ni láti fi hàn gbogbo àgbáyé irú ìwà abúrú tó n wáyé ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti bí ìjọba ààrẹ Muhmamadu Buhari ṣe fá orí apákan dá apákan sí nínu ètò gbogbo.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹ̀nusọ fún ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye Maxwell Adeleye fi síta lo ti ṣàlàyé pé ìwọ́de náà yóò ṣe àfihan gbogbo ìwà ìpàniyan tó n wáyé ní Nàìjíríà nípasẹ̀ àwọn darandaran.

Ó ní àwọn darandaran náà lábẹ́ ìbòjú kíkó ẹran jẹ̀ ni ìhà gúúsù àti gbùngbùn Nàìjíríà ni wọ́n fi hùwà ọ̀daràn tí ìjọba náà sì ń dáàbò bò wọ́n láti máa hùwà ibi.

Ọjọ́gbọ́n Akintoye, ní àwọn ènìyàn Gúúsù, àtí gbùngbùn nàìjíríà yóò máá fí han gbogbo ayé bí ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe ń hùwà ìkà sí ọmọniyan, gbígbógun ti ẹ̀tọ́ láti sọ èrò ara ẹni, ati sísọ̀rọ̀ lái bẹ̀rù ẹnikẹ́ni, tó fi ma ìwà ọ̀daràn mííràn tí ìjọba ààrẹ Buhari ń hù.

Bákan náà ni ìwọ́de ọ̀hún ń pè fún fífí òpin sí ìwé òfin 1999 tí wọ́n fi ń hu ìwà ọ̀daràn sí àwọn ènìàn Nàìjíríà

Ìwọde náà bí wọ́n ṣe sọ yóò tú àṣírí si gbogbo ayé bi àwọn ẹ̀yà répété sẹ ń fi ipá gba nǹkan ìní àwọn ẹ̀ya gúúsù àti àwọn gbùngbùn Nàìjíríà, èyí tí wọ́n fẹ̀sùn pé wọ́n gbé kalẹ̀ láì fi lọ ẹnikẹni.

Bákan náà ni wọ́n pè pé kí àjọ UN kéde ẹgbẹ́ Miyetti Allah gẹ́gẹ́ bi ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí

Òní lòní ń jẹ́, ìwọ́de ènìyàn mílíọ̀nù kan yóò wáyé ni New York lórí òmìnira ìran Yorùbá

Yoruba Nation: Òní lòní ń jẹ́, ìwọ́de ènìyàn mílíọ̀nù kan yóò wáyé ni ni New York

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Láti bi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ àpapọ̀ ọmọ bíbí Nàìjíríà tó kóra jọpọ̀ láti dá dúró (NINAS) tí n kéde pé ìwọ̀de ènìyàn mílíọ̀nù kan yóò wáyé ni New York lónìí tíí ṣe ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹsàn ọdún 2021.

Ìpè yìí ló wà fún bíbèrè fún ìbò bẹ́ẹ̀ni bẹ́ẹ̀kọ́ láti dúró tàbí yapa kúrò ní Nàìjíríà àti wíwọ́gilé ìwé òfin Nàìjíríà ọdún 1999.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

Iwọ́de náà yóò wáyé níwájú olú ilé iṣẹ́ àjọ ìsọkan àgbáyé ní New York lásíkò ìpàdé apérò àjọ UN ẹ̀lẹ́kẹrìndílọ́gọ́rin irú rẹ̀ tó n bẹ̀rẹ̀ lónìí.

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ NINAS tó gbé ètò náà kalẹ̀ ṣe sọ, ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye ni yóò léde ètò náà nígbà tí, ọjọ́gbọ́n Yusuf Turaki tó jẹ́ àkọ̀wé gbogboogbò NINAS àti Tony Nnadi tó fí mọ́ àwọn mííràn náà yóò péjú síbẹ̀.

Àkọlé fídíò, Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

Àwọn tó darapọ̀ láti di ọmọ ẹgbẹ́ NINAS tó n dari gbogbo ẹgbẹ́ tókù tó n pinu láti dá dúró ni àwọn ọmọ ìhà gúúsu, ààrin gbùngbùn Nàìjíríà, pẹ̀lú Ilana Omo Oodua tó n sójú fún ẹ̀yà Yorùbá, àwọn ẹ̀yà ìhà apá ìsàlẹ̀ Niger tó n sojú fún South- South àti South- East.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Bákan náà ni ẹgbk náà pè fún kí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, ran àwọn ọmọ ogun aláàbò àjọ ìsọkan àgbáyé wá sí Nàìjíríà láti wa bèrè fún ìdìbò bẹ́ẹ̀ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ lórí ipinu àwọn ẹ̀yà tó fẹ́ dá dúró nípa kíkúrò lábẹ́ ìṣèjọba Nàìjíríà.