Monsurat Police Stray Shooting: Odumosu ṣé àbẹwò sí ìdílé Monsurat tí ọlọ́pàá yìnbon lú

Ile awọn Monsurat

Kọmisana ọlọpaa ni ipinlẹ Eko Hakeem Odumosu ti ṣe abẹwo si mọlẹbi arabinrin Monsurat Ojuade ti ibọn ba ni adugbo Ijeshatedo.

Ọrọ yi jẹyọ ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa Eko,Adekunle Ajisebutu fi sọwọ sawọn akọroyin.

O ni lasiko abẹwo rẹ, Kọmisana kọwọrin pẹlu awọn ọga agba ọlọpaa nipinlẹ naa ti wọn si ba mọlẹbi Monsurat kẹdun iku arabinrin naa.

Ọ̀gá Ọlọ́pàá

Bẹẹ naa lo fi iwe ikẹdun jiṣẹ fun mọlẹbi to tun fi to wọn leti pe awọn ti mu ọlọpaa to yinbọn pa Monsurat,iyẹn Sajẹnti Samuel Philips.

O ni igbẹjọ labẹle n lọ lọwọ lori Philip.

Ni ọjọ Kọkanla oṣu Kẹsan ni aṣita ọta ibọn ba Monsurat.

Ọwọ́ tẹ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa ọmọ ọdún 18 nílùú Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ti fi ṣikun ofin mu ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ to yinbọn pa ọmọ ọdun mejinlogun kan nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Adekunle Ajisebutu lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn akọroyin bo tilẹ jẹ pe o kọ lati fi orukọ tabi aworan afurasi naa lede.

Atẹjade ọhun ni "O ti tẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko leti pe aṣita ibọn ba ọmọ ọdun mejidinlogun kan, Monsurat Ojuade ni nnkan bii aago kan oru, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021, lasiko ti awọn ọtẹmuyẹ CID lọ ṣawari awọn adigunjale kan ni Ijeshatedo."

Àkọlé fídíò, Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

"Wọn gbiyanju lati doola ẹmi ọdọbinrin naa ṣugbọn o jade laye lasiko ti wọn n gbe lọ sile iwosan."

Ajiṣebutu tẹsiwaju pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ba ẹbi oloogbe naa kẹdun.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

O fikun pe ọwọ awọn ti tẹ ọlọpaa to yinbọn pa ọmọ naa ati pe iwadii ti bẹrẹ, afurasi ọhun yoo si foju bale ẹjọ laipẹ lẹyin ti wọn ba ti kọkọ gba iṣẹ lọwọ rẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni eyii yoo jẹ arikọgbọn fun awọn ọlọpaa to ku ti wọn n ṣiṣẹ wọn bii ẹni ti ko ni ẹkọ to dantọ.

Lẹyin naa lo ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii ti ko fun ileeṣẹ ọlọpaa lorukọ rere, awọn yoo tẹsiwaju lati maa dabo bo awọn araalu ati dukia wọn.

Ẹwẹ, lasiko ti ikọ BBC ṣabẹwo sile oloogbe naa lọjọ Aiku, inu ibanujẹ ọkan ni awọn mọlẹbi rẹ wa, ti wọn si n bere fun idajọ ododo lori iku aitọjọ to mu ọmọ wọn lọ.