Gumi visits Igboho: Àwọn èèyàn ìlú Igboho ní Sheikh Gumi wọ ìlú náà bí olè lóru

Awọn ọmọbibi ilu Igboho nipinlẹ Oyo ti ke gbajare pe awọn ko mọ ohun kan nipa abẹwo Sheikh Gumi, koda wọn ni awọn ko gbabọde fun un.
Lemaamu, olori ọdọ, alaga ilu, olori awọn musulumi, Ifa Igboho atawọn eeyan ilu naa mii lo korajọ pọ ti wọn si fidi ọrọ yii mulẹ ninu fọnran kan ti wọn fi sita lori Facebook.
Wọn ni bi ole loru ni Gumi ṣe wọ ilu Igboho lai kan si ọba ilu naa tabi olori kankan.
- Kílódé tí Sheikh Gumi fi ṣe àbẹ̀wò sí Igboho nínú gbogbo ìlú tó wà nílẹ̀ Yorùbá?
- Ìwádìí ti tú àṣírí àwọn tó yìnbọn lu olùwọ́de EndSARS ní Tollgate l'Eko
- Darandaran tó bá rúfín dída ẹran nígboro l'Ondo rugi oyin- Akeredolu yarí
- Ìjì tó hú igi ńlá ní ìtẹ́ òkú l'Eko ba ibojì òkú 50 jẹ́, àwọn ẹbí sáré lọ w'òkú wọn
- Wo iye mílíọ̀nù tí Miyetti Allah yóò máa ta màálù kan tí ìpínlẹ̀ Eko bá fòfin de ìdẹranjẹko ní gbangba
- Àwọn jàndùkú agbébọn jí òṣìṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo mẹ́ta lọ
Gbogbo wọn ni pa ẹnu pọ sọ pe ọba tabi adari ilu Igboho kankan ko gba owo lọwọ Gumi nigba to ṣabẹwo si ilu Igboho.
Wọn ni ti Gumi ba jẹ musulumi ododo, niṣe lo yẹ kọ lọ ba ọba ilu ki o si lọ kirun ni mọṣalaaṣi.
Ṣugbọn wọn ni Gumi ko ṣe bẹẹ, o wọ ilu Igboho bi ole loru ni.
Wọn wa rọ Gumi wi pe ko gbọdọ pada si ilu Igboho mọ bi bẹẹ kọ, yoo kan idin ninu iyọ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
''Ti Gumi ba n lọ ibi kibi, ko ṣọra ṣe, tori ilu Igboho kii ṣe ilu ti eeyan kan le maa wọ bi o ṣe wu u.
Irinajo Sunday Igboho si Benin Republic yẹ Ọlọrun to ṣe ẹda gbogbo wa.
A si gbagbọ pe ori naa lo maa ko o yọ ninu ọfin to wa ni Cotonou.
Eeyan pataki ni OLoye Sunday Igboho nilẹ Yoruba, tori naa gbogbo wa ni a wa lẹyin rẹ.
Ọmọ Akin ni Igboho, ọmọ Akin kii ṣojo, bi gbogbo awọn ọmọ ilu Igboho ṣe ri niyẹn,'' awọn ọmọbibi ilu Igboho lo sọ bẹẹ.
Àbẹ̀wò Sheikh Gumi sí ìlú Sunday Igboho ń bí mi nínú, Gani Adams bínú tán
Aareonakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams atawọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ ẹṣọ eleto abo nilẹ Yoruba ti bẹnu atẹ lu abẹwo alarina awọn janduku agbẹbọn, Sheikh Ahmad Gumi si ilu Igboho tii ṣe ilu Oloye Sunday Adeyemo.
Ilu Igboho ni olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ Oorelope ni ipinlẹ Oyo nibi to jẹ orirun Igboho fun ra rẹ.
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni fọnran kan lu ayelujara pa ninu eyi ti awọn eeyan ti ri Gumi ati ọga ajọ NHIS tẹlẹ ri, Ọjọgbọn Usman Yusuf.
Iba Gani Adams ṣapejuwe abẹwo Gumi silu Igboho gẹgẹ bi ohun to binu ninu.
Gani sọrọ yii ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ igbimọ to n ri si eto abo nilẹ Yoruba fi sita ninu eyi ti wọn kilọ fawọn janduku agbebọn pe ki wọn jina rere si ilẹ Yoruba.

Wọn ni ọna lati pẹgan ati lati gbegi dina akitiyan awọn ajijagbara ilẹ Yoruba ni abẹwo Gumi si ilu Igboho jẹ.
Igbimọ to n ri si ọeọ eto abo nilẹ Yoruba tun sọ pe bi Gumi ṣe n sọrọ ninu fọnran naa fihan pe oun lo wa lẹyin iṣẹlẹ ikọlu DSS si ile Igboho to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan.
''Ọmọ Naijiria ni Gumi, o si lẹtọọ lati ṣe abẹwo si ibi kibi to wu u ni Naijiria.
Ṣugbọn kii ṣe bi ko lọ si ilu abinibi Sunday Igboho lati maa tako akitiyan rẹ lori idasilẹ orilẹede Yoruba.
Iwa to bini ninu eyi, o si le da rogbodiyan silẹ.
O dabi ẹni pe awọn janduku agbebọn ti n gbero lati kọlu ilẹ Yoruba ṣugbọn a ko ni gba fun wọn.
A fi asiko yii rọ awọn agbofinro ati gbogbo awọn ẹṣọ eleto abo lati wa lojufo bayii ju ti atẹyinwa lọ nilẹ Yoruba.












