Workers ex-President Obasanjo Kidnap: Ọlọ́pàá ti dóòlà òṣìṣẹ́ ààrẹ tẹlẹ, Olusegun Obasanjo sílẹ lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n jí wọn gbé

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, other

Awọn oṣiṣẹ aarẹ tẹlẹ Olusegun Obasanjo mẹta to ko si ọwọ awọn ajinigbe ti gba itusilẹ leyin nkan bi wakati mejidinlaadọta.

Ni irọlẹ Ọjọru ni a gbọ pe wọn ji wọn gbe ni ìjọba ibilẹ Obafemi owode ki wọn to tu wọn silẹ ni irọlẹ ọjọ Ẹti.

Alukoro ọlọpaa Abimbọla Oyeyemi to fidi ọrọ yi mulẹ sọ pe akitiyan awọn agbofinro lo mu ki awọn ajinigbe naa tu awọn oṣiṣẹ yi silẹ.

O ni lati igba ti won ti ji wọn l'awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọ inu igbo tọ awọn ajinigbe ọhun lọ.

"Lati ana l'awọn ìkọ ọtẹlẹmuyẹ wa ti n dun koko mọ awọn ajinigbe taa sì ti n tọ pínpín wọn"

O tẹsiwaju pe àwọn to ipasẹ wọn dé igbó to wa lẹyìn ilé ẹkọ girama Day Waterman College.

"Ibẹ ni wọn wa lati ana"

Alukoro ọlọpaa naa ko sọ nkankan nipa boya wọn mu awọn ajinigbe naa tabi pe wọn doju ija kọ wọn. Bakan naa a ko ri aridaju boya wọn san owo itusilẹ fawọn ajinigbe.

Àwọn jàndùkú agbébọn jí òṣìṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo mẹ́ta lọ

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, other

Awọn janduku agbebọn ti ji oṣiṣẹ aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Olusegun Obasanjo lọ ni abule kan lẹgbẹ Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Ọjọru.

Iroyin sọ pe awọn agbebọn ọhun gẹgun de awọn oṣiṣẹ naa labule Kobape ni ijọba ibilẹ Obafemi-Owode nipinlẹ Ogun.

Iroyin naa sọ pe alakoso ọrọ owo, ayẹwe owo wo ati adari ileeṣẹ ni awọn oṣiṣẹ mẹta Obasanjo ti wọn ji gbe lọ.

Bi ago mẹrin irọlẹ ni wọn ji awọn eeyan naa lẹyin tawọn agbebọn ọhun yinbọn si ọkọ Hilux tawọn oṣiṣẹ naa wa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi, lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

Oko Obasanjo ko jina si agbegbe Kobape ti wọn ti ji awọn eeyan naa gbe lọ.