Sunday Igboho trial: Olùdarí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ Igboho kéde ìgbésẹ̀ lórí àwọn agbẹjọ́rò tó ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ní Cotonou

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho

Oludari igbimọ igbẹjọ fun Sunday Igboho, Olasupo Ojo ti kede pe Igboho ko paarọ awọn amofin to n ṣoju rẹ ninu igbẹjọ to n lọ ni orilẹ-ede Benin Republic.Igboho sọrọ ninu fónrán kan pẹlu ibinu pe niiṣe lawọn agbẹjọro mẹwàá to n ṣoju rẹ kan n gba obitibiti owo, sibẹ òun sì wà ní atimọle ni Cotonou.Igboho ni awọn amofin mẹwàá yii kò tíì rí nkan ṣe sí bi oun ti wa ni atimọle fún bí aadọta ọjọ bayii.

Ajijagbara ilẹ Yoruba sọ ninu fónrán náà pé awọn naa ti Ọgbẹni Ibrahim Salami jẹ olori wọn fi oun silẹ ni ẹwọn lai bikita.Igboho fi aidunnu rẹ hàn s'awọn agbẹjọro naa lori bi wọn ṣe n ṣe si oun lẹyin ti ẹni kọọkan wọn ti gba miliọnu márún ùn marun un tan.Igboho ni oun o tiẹ bẹrù ki wọn gbe oun pada si Naijiria nibi ti igbẹjọ oun dé dúró bayii.Ṣugbọn adari igbimọ Igboho ti sọ pe awọn agbẹjọro naa ni yóò máa tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ náà ni Cotonou.

Àkọlé fídíò, Lóòtọ́ orin mi àti Lagbaja jọra ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ díẹ̀ wà níbẹ - Labule

"A mọ awọn agbẹjọro to n ṣiṣẹ, bakan naa ni a mọ awọn ti ko ṣiṣẹ. A ti gbe igbesẹ ṣugbọn a ko da ẹnikẹni duro ninu wọn. Gbogbo wọn lo ni anfani kan tabi omiran ti wọn lori igbẹjọ yii. Ẹ maa gbagbe pe ilẹ okeere ni

igbẹjọ ti n waye. Idi niyii ti a fi n tẹsiwaju pẹlu gbogbo wọn, a lè dari wọn lori ohun ti a ba fẹ. Igboho le ma mọ iṣẹ tawọn amofin naa n ṣe, oun kan mọ nipa awọn ti o n foju ri ni. Gbogbo wọn kò lè máa yoju síi lẹwon,"

Ọgbẹni Ojo lo ṣalaye bẹẹ.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho ni Naijiria, Pelumi Olajengbesi ni inu igbimọ igbẹjọ ko dun si aawọ laarin aṣiwaju awọn to pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba naa atawọn amofin rẹ ni orilẹede Benin Republic.Olajengbesi ni Igboho mọ ilọsiwaju to wa lori igbẹjo rẹ niluu Abuja ati Ibadan ṣugbọn inu rẹ ko dun sí bi ọ sí ti wa lẹwon ni Cotonou.