Sunday Igboho: Ìgbẹ́jọ́ yóò wáyé ní Ibadan lórí ẹjọ́ tí Sunday Igboho pe DSS àti Malami

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho/Instagram

Igbẹjọ yoo tẹsiwaju loni lori ẹjọ ti ajafẹtọmọniyan,Sunday Adeyemo,Igboho, pe ijọba apapọ Naijiria lori idaabo bo ẹtọmọniyan rẹ.

Lọwọlọwọ bayi Sunday Igboho wa ni ahamọ ni orileede Benin nibi ti awọn alaṣẹ ilẹ naa ti n ba ṣẹjọ.

Nipa ẹjọ to n waye loni ni Naijiria, adajọ ti ṣaaju ni ki awọn agbe fun ijọba ati Minisita feto idajọ ma ṣe dunkoko mọ Sunday Igboho.

Ninu ohun ti adajọ sọ, o ni wọn ko gbọdọ fọwọ kan akoto owo Igboho bẹẹ si ni o lanfaani lati yan fanda nilu lai si idiwọ lọdọ ijọba tabi awọn agbodegba rẹ.

Ẹmeeji ọtọọtọ ni ile ẹjọ ti da Igboho lare lori ẹbẹ ti agbẹjọro agba Naijiria fi tako idajọ ti adajọ gbe kalẹ.

Adajọ Ladiran Akintola lo n dari ẹjọ naa ni ile ẹjọ giga to wa nilu Ibadan.