Life at 40: Ìbálòpọ̀ àti nkán márùn-ùn míì tí o lè ṣé kí ará rẹ̀ fí jí pépé tó bá pé ogójì ọdún

Awọn dokita onimọ nipa ibalopọ tun sọ pe ibalopọ maa n ran tọkọ taya lati gbaradi fun ipenija.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibi agba ba de duro, bo pẹ boya ọmọde yoo pada de ba wọn nibẹ.

Eyi lo difa fun bi pupọ awọn to jẹ ọdọ ṣe n gun oke agba ni meni meji ti agba si n kan onikaluku.

Bi eeyan ba ti wa gun oke agba to di ẹni ogoji ọdun, ọ̀pọ̀ nǹkan to maa n ṣe ni yoo bẹrẹ si ni gba ọna mi yọ.

Yala nipa ounjẹ jijẹ ni tabi ibaṣepọ koda to fi mọ aṣọ wiwọ, diẹ ree ninu awọn nkan ti eeyan le ṣe lẹyin to pe ogoji ọdun ki ara rẹ le ji pepe

Rii wi pe o n mu omi daada

Omi mimu ni anfaani to n ṣe fun ara ṣugbọn o ṣeni laanu pe agbara awọn ẹya ara to n lo omi yi a maa dinku bi eeyan ba ti re si ogoji ọdun.

Nitori eyi, pupọ eeyan to ba ti n dagba ni ko ni maa gbẹ oungbẹ omi mimu ti eleyi si le ṣe akoba fun ara wọn.

Aworan omi to wa ninu ikeemu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wahala le de ba kidirin ẹni ti ko ba mu omi daada tabi ki oyi fẹ maa kọ.

Tori naa ri pe o mu omi daada ati loore koore bo ba ti gun oke agba de ogoji ọdun

Mimu ọti waini pupa (Red Wine)

Gẹgẹ bi iwadii kan tawn onimọ ṣe lori mimu ọti waini pupa, wọn ni o wa lara awọn ohun ta le fi koju didarugbo lojiji.

Awọn eronja to wa ninu ọtiwaini yi bi anti oxidants a maa mu ki ara eeyan ṣe jọlọ daada.

aworan ọti waini pupa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iwaddi ọhun sọ pe tori pe waini pupa da bii ti ka mu lamupara kọ

Ikeemu kan tabi meji ọti waini pupa yi lojumọ loore to pọ fun alaafia ara bi eeyan ba ti n gun oke agba lọ.

Ninu awọn aisan to le fi waini koju ni aisan itọ ṣuga.Bẹẹ lo si le ko ni yọ lọwọ aarun jẹjẹrẹ to fi mọ aisan kan ti orukọ rẹ n jẹ Alzheimer

Ibalopo loore koore

Ọpọ eeyan lo maa n ro pe bi eeyan ba ti n dagba lọ, erepa inu iyara laarin lọkọ laya gbọdọ maa diku.

Ọrọ ko ri bẹ rara.

Iwaadi ti fi han pe ibalopọ laarin tọkọtaya a maa mu ki ara wọn ji pepe, ki irun wọn maa dan daada ki wọn si ma tete darugbo loju.

Ọ̀kùnrin àti obìnrin

Ninu iwadii awọn tọkọtaya ẹgbẹrun lọna ọgbọn, awọn onimọ ri pe awọn to n ni ibalopo o kere tan lẹẹmẹtaa lọsẹ ko tete gbora bi awọn akẹgbẹ wọn ti ko ṣe bẹ.

Onimọ nipa itọju awọ ara,Keira Barr,ni idamira lasiko ibalopọ a maa tu kẹmika kan jade ti a mọ si Oxytocin.

Oxytocin yi a maa jẹ ki ara eeyan balẹ daada ti ko si ni jẹ ki ara eeyan hunjọ pupọ.

Sisun oorun daada ju ti tẹlẹ lọ

Ara eeyan ni aimasundeede maa n fi abọ si.

Bi eeyan ba si ti n sunmọ ogoji ọdun, ko yẹ ko maa jẹ gbese orun lai san pada.

Iwadii kan fi han pe awọn ti o sunmọ ogoji ọdun ti kii ri oorun sun deede a maa yara darugbo ju awọn akẹgbẹ wọn to n sun daada lalẹ.

Obinrin to sun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara awọn nkan ti aisun deede maa n ṣe lakoba ni pe awọ ẹni ti ko sun daada ko ni dan mọran lẹyin to ba jade si inu orun.

O kere tan rii pe o sun oorun wakati mẹjọ nitori eleyi ni ọpọ oore to n ṣe fun ara rẹ to ba ti pe ogoji ọdun tabi ju bẹ lọ.

Ṣọ iru ounjẹ ti o n jẹ

Ounjẹ lọrẹ awọ lootọ ṣugbọn bi eeyan ba ti gun oke agba, o di dandan lati maa sọ iru nkan ti yoo maa jẹ.

Bi o ba nifẹ si ki awọ rẹ jọlọ biigba ti o ṣi wa lọdọ, rii pe o mu ayipada ba nkan to maa n jẹ tẹlẹ.

Ounjẹ to dara fun ara bi eso, ẹfọ,ounjẹ ti ko lọra lara pupọ maa n jẹ ki eekanna,irun ati awọ eeyan maa dan mọranmọran.

Eso ati Ewebẹ to yi wa ka

Yago fawọn ounjẹ alagolo,ṣuga pupọ ati ounjẹ to kun fun ọra ti ko ṣeni laanfani.

O tọ ki o mu adinku ba iyọ jijẹ nitori eleyi a maa jẹ ki ifunpa rẹ ga ju ti tẹlẹ lọ.

Maa rẹrin si ju ti tẹlẹ lọ

Fifa oju ro ni gbogbo igba, akoba lo maa n ṣe fun ara.

Ẹrin arinju naa ko da ṣugbọ, ju tatẹyinwa lọ, rii wi pe o n fi ẹrin da inu ara rẹ dun loore koore.

Aworan arakunrin kan to n rẹrin

Oríṣun àwòrán, Instagram/Neduwazobia

Ẹrin rinrin maa n jẹ ki eeyan pa ironu rẹ,bẹẹ si ni a maa jẹ ki eeyan dabi pe o lo ajidewe.

Awọn onimọ sọ pe ẹrin rinrin da bi idaraya fun ọkan, a si maa jẹ ki ẹjẹ gba ibi to ba yẹ ninu ara ti eleyi ko si ni jẹ ki eeyan tete darugbo.